Bi ẹ
ṣe n ka iroyin lọwọlọwọ, iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ni pe gbajumọ oṣerebinrin
nni, Toyin Aimakhu ti wa ninu oyun, ko si ni pẹ ẹ bimọ.
Fawọn
to n ba n ṣakiyesi fọto ti ọmọ bibi ilu Ẹdo n gbe sori ẹka ayelujara lẹnu ọjọ
meloo kan bayii, wọn yoo ri i daju pe oyun naa ti yọ sita kọja nnkan ti wọn n
fi pamọ, nitori pe gedengbe bayii ni kinni naa ti yọ sita.
Kii ṣe
ahesọ mọ pe gbajumọ oṣerekunrin nni, Kọlawọle Ajeyẹmi tawọn eeyan tun n pe ni
Awilo ni Toyin Aimakhu n fẹ bayii, lẹyin ti wọn ti ṣe eto mọmi-n-mọ-ẹ, iyẹn
introduction laarin mọlebi wọn, ta a si gbọ pe igbeyawo bonkẹlẹ lawọn mejeeji
ṣe.
Awilo, ọkọ Toyin |
Lẹyin ti Toyin ati Adeniyi ja, lobinrin naa pada sọdọ Ṣeun Ẹgbẹgbẹ to ti kọkọ fẹ ri, ki aarin wọn tun too daru.
Ju
gbogbo ẹ lọ, ọjọ ti ariwo 'Ẹ ku ewu ọmọ' yoo sọ nile awọn Toyin la wa n
reti bayii.
No comments:
Post a Comment