O MA ṢE O: EYI NI BAWỌN TỌỌGI ṢE DANA SUN ỌFIISI ỌNỌREBU OLUỌMỌ N'IFỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 22, 2019

O MA ṢE O: EYI NI BAWỌN TỌỌGI ṢE DANA SUN ỌFIISI ỌNỌREBU OLUỌMỌ N'IFỌ

Ko sẹni to de agbegbe Banki to wa n'Ifo, ipinlẹ Ogun lọjọ Sande ana, to ri bawọn tọọgi ṣe dana sun ọfiisi igbakeji olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnọrebu Ọlakunle Oluọmọ ti ko ni i ba ọkunrin naa kẹdun, paapaa bi wọn tun ṣe dana sun bọọsi marun ti ọkunrin naa fi n ko awọn ọmọ ileewe lojoojumọ.

Ọnọrebu Oluọmọ
Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ jẹ ko ye wa pe ọjọ Sande ana ni wọn ṣayẹyẹ ọdun Akoogun n'Ifo to si jẹ pe ọkan lara awọn ọdọ agbegbe naa ti wọn loo ṣiṣẹ tako ẹgbẹ oṣelu APC ninu idibo to kọja yi lo ranṣẹ pe awọn tọọgi wa sibi ayẹyẹ naa lati wa da a ru.

Ohun ta a gbọ ni pe nibi ti wọn ti n ṣayẹyẹ naa lọwọ lawọn ọlọpaa SARS ti de bẹ, wọn ni ọkan lara awọn ọdaran ti wọn ti n wa tipẹ ni wọn wa de bẹ, bi wọn si ṣe ri ẹni ti wọn wa wa, ti wọn tun ba ibọn lara awọn kan ninu wọn ni wọn lawọn tọọgi naa ti bẹrẹ wahala pẹlu wọn.

Lojiji ni wọn lawọn kan ti bẹrẹ si i fẹsun kan Ọnọrebu Oluọmọ to n ṣoju ẹkun Ifo nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun pe oun lo ran awọn SARS wa lati wa a ko awọn ti ko gba ti ẹ lagbegbe naa.

Eyi gan an ni wọn loo bi awọn tọọgi naa ninu, ti wọn si gba ọfiisi ọkunrin naa lọ lati dana sun un.

A gbọ pe awọn bọọsi nla marun ti ọkunrin naa ra pe ki wọn maa fi ko awọn akẹkọọ agbegbe naa lọ sileewe lojoojumọ ni wọn dana sun kọja afẹnusọ, ti wọn si tun dana sun ọfiisi naa, to jona rau-rau.

bi iroyin naa ṣe tẹ Ọnọrebu Oluọmọ lọwọ la gbọ pe o ti ranṣẹ sijọba ipinlẹ Ogun pe ki wọn gba oun lọwọ awọn to n lepa ẹmi oun, ati pe gbogbo dukia oun ni w'ọn ti dana sun.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI