ẸTANU NI GOMINA AMOSUN FI JA AYẸYẸ ỌDUN ILU ILẸ AFRIKA GBA LỌWỌ MI – BAṢỌRUN ỌLADIPỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 16, 2019

ẸTANU NI GOMINA AMOSUN FI JA AYẸYẸ ỌDUN ILU ILẸ AFRIKA GBA LỌWỌ MI – BAṢỌRUN ỌLADIPỌ

Kọniṣọna tẹlẹ fọrọ Aṣa ati Irin Ajo Afẹ nipinlẹ Ogun, Baṣọrun Muyiwa Ọladipọ ti sọ ọ sita gbangba pẹ ẹtanu ni Gomina Ibikunle Amosun fi ja ayẹyẹ ọdun Ilu Ilẹ Afrika, iyẹn African Drum Festival gba lọwọ oun nitori pe nigba toun gbe eto naa kalẹ, Gomina Amosun ko gba a wọle, ṣugbọn nigba to ri i bawọn eeyan ṣe kan saara soun lẹyin ayẹyẹ naa, lo ba pinu lati gba eto naa kuro lọwọ oun. Ẹ ka bi ẹkunrẹrẹ ifọrọwerọ naa ṣe lọ pẹlu akọroyin wa.

IBEERE: Nj a le mọ yin lẹkunrẹrẹ?
AWIKONKO: Orukọ temi ni Baṣọrun Muyiwa ladip, mo ti figba kan ri jẹ olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, mo tun ti figba kan ri jẹ Kọmiṣọna fun eto oye jijẹ ati ijọba ibilẹ, bẹẹ ni emi ni Kọmiṣọna fun eto Aṣa ati irin ajo afẹ to ṣẹṣẹ fipo silẹ, iyẹn nipinlẹ Ogun kan ṣoṣo yi.

IBEERE: Oriṣiriṣi awuyewuye lo n lọ nita pe wahala wa laarin ẹyin ati Gomina Ibikunle Amosun lo jẹ ki ẹ kuro ninu ẹgbẹ rẹ, ṣe lootọ ni?
AWIKONKO: Wel, Owe Yoruba kan lo sọ pe, ‘Ogun ọmọde ko le ṣere fun ogun ọdun’asiko iyapa yoo wa ṣa a ni, ko nii ṣe pẹlu iye igba ti ẹ fi jọ n ṣe ọrẹ bọ. Nkankan ni yoo ṣe sababi b'onikaluku yoo ṣe lọ lọtọọtọ, ṣugbọn ni ti Gomina to ṣẹṣẹ n fipo silẹ yi ati emi, nnkan bi ọdun bi ọdun mẹrinla sẹyin la pade, ati pe gẹgẹ bi iru eeyan ti mo jẹ, mo jẹ ẹni kan to n bọwọ fun eeyan pupọ, bi mo ba si pinu lati kuro lẹyin eeyan, ko si pe mo tun n boju wẹyin mọ. Wipe mo kuro lẹyin Sẹnetọ Ibikunle Amosun jẹ nipa ilana mi (progressive). Akọkọ ni pe, mo jẹ ẹni to nifẹ si ilọsiwaju, mi o kii ṣe ẹni to maa n binu fufu (reactionary). Nipasẹ ibinu fufu ni wọn fi da ẹgbẹ oṣelu APM silẹ, ko fẹsẹ mulẹ daadaa. Ironu igbẹyin ni, o si di dandan ko kuna laipẹ. ṣe lo dabi owe kan to sọ pe ‘ile ti a ba fi it m, iri lo ma wo o’. Igba diẹ lasan naa ni, wọn ko da a silẹ nipasẹ iṣotitọ, nitori naa, o gbọdọ lọ, idi ni yii ti gbogbo awọn eeyan nipinlẹ Ogun fi kọ ẹyin wọn sii, lai nii ṣe pẹlu iye ibo ti wọn sọ pe awọn ni. O fẹẹ jẹ pe idameji ibo ti wọn sọ pe awọn ni lo jẹ pe eyi ti wọn fowo ra ni, ẹ ko le yọwọ fifowo ra ibo kuro ninu ibo ti wọn ni.

Bi ẹ ba jẹ ẹni to maa n gba agbegbe Ibara nibi ti Gomina Amosun kọ ile ẹ si, ẹ maa ṣakiyesi pe ọsẹ meji sasiko idibo, ṣe ni ile Gomina Amosun dabi ibi ẹrọ tawọn eeyan ti n gba owo, iyẹn ATM, gbogbo eeyan lo n lọ sibẹ lati lọọ gba owo nibẹ, iyẹn ko si jẹ nkan babara fun wa nitori pe ifẹ Ọlọrun ni yoo bori ifẹ ọkan eniyan. Gomina Amosun ti rin jinna lati maa ṣebi Ọlọrun, mo si kilọ fun un nigba naa pe ko yee ri ara rẹ gẹgẹ Ọlọrun.

IBEERE: Bawo gan-an ni Gomina Amosun ṣe n ṣe bi Ọlọrun?
AWIKONKO: Bẹẹni, nipa bo ṣe n lọ kaakiri lati sọ fun gbogbo agbaye pe oun loun yoo fa Gomina ti yoo gba ipo lọwọ oun kalẹ. To si tun n mu ẹni naa kaakiri pe ẹni ti yoo maa ṣe Gomina le wọn lori ni yii. Ọpọ igba ni mo kilọ fun un nigba naa, ṣugtbọn ko gbọ.

IBEERE: A tiẹ gbọ pe ọpọ nnkan lẹ fi jin fun Gomina Amosun, ṣugbọn ṣe lo fi ibi ṣuu yin. Ṣe lootọ ni? Idi ni pe, bo ṣe muu yin kuro nilẹ to n ṣan fun wara ati oyin lọ silẹ gbigbẹ.
AWIKONKO: Mi o gba iyẹn wọle pe o mu mi lọ silẹ gbigbẹ, nnkan to nii ṣe pẹlu iṣẹ ijiyin ni. Bi ẹ ba wo o daadaa, ko yẹ ki ẹ ri gbigbe ti wọn gbe e yin lati ibi kan sibo min in gẹgẹ bi ifiyajẹni. O le fẹẹ jẹ bẹ, ṣugbọn ẹ jẹ ki n fi ti Bibeli ṣapẹẹrẹ fun yin. Awọn ẹgbọn Josẹẹfu ta a si oko ẹru lero wipe yoo ku, ṣugbọn fun pe wọn ta a si oko ẹru gan an lo tun gbe ayanmọ ẹ soke, to fi di Apaṣẹ. Eyi gan an lo lọ nibamu pẹlu nnkan to ṣẹlẹ si mi. Ewe kan ko le jabọ lara igi ki Ọlọrun ma mọ nipa ẹ.

Lero ọkan Gomina Amosun, o le dabi i pe oun fiya jẹ mi loju ẹ, ṣugbọn mo fẹ ki ẹ gba mi gbọ pe mo ṣaṣeyọri nipa Kọmiṣọna fun eto Aṣa ati Irin Ajo Afẹ. Ko si bi wọn yoo ṣe sọ itan Ayẹyẹ Ilu Ilẹ Afrika, iyẹn African Drum Festival ti yoo pe lai darukọ Baṣọrun Muyiwa Ọladipọ.

IBEERE: Bi a ba wo o ninu itan, ileeṣẹ eto ijọba ibilẹ ati ọrọ oye jijẹ lo jẹ igi lẹyin ọgba fun iru aṣeyọri yoo wun ti Gomina ba ṣe, eyi ti wọn ti yọ yin kuro. Latigba ti wọn ti yọ yin kuro nileeṣẹ naa ko ti ṣe daadaa mọ. Ṣe ka sọ pe inu yin dun bi wọn ṣe yọ yin ni?
AWIKONKO: Wel, ipinu atọkan wa niyẹn. Bi ẹ ba fi ara yin silẹ lati sin awọn eeyan, tabi ka sọ pe wọn yan yin lati sin awọn eeyan, ẹ ni lati maa bọwọ fun gbogbo eeyan, o si gbọdọ sẹtan lati ṣiṣẹ isin ni eyikeyi ọna to pọ. Ki la o ba maa sọ kani wọn ko yan mi si ileeṣẹ eto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ lakọkọ? Ki la o ba sọ to ba jẹ pe ileeṣẹ Aṣa ati Irin Ajo Afẹ ni wọn kọkọ gbe mi si. ṣugbọn sibẹ, kani ibi ti mo ti bẹrẹ naa niyẹn, ọpọ awọn eeyan ni wọn le ti ri awọn nnkan ti mo ti ṣe nibẹ yẹn, eyi lo fa a to fi jẹ pe oriṣiriṣi nnkan lawọn eeyan tunmọ ẹ si i nigba ti wọn gbe mi kuro nibẹ lọ si ileeṣẹ Aṣa ati Irin Ajo Afẹ, ṣugbọn ti mi o tiẹ rii ro rara.

Fun pe wọn gbe mi lọ si ileeṣẹ Aṣa ati Irin Ajo Afẹ tun fi kun orukọ mi ni, to si tun jẹ ki n gba iyi kọja afẹnusọ. Ọpọ awọn eeyan ni wọn n wo o pe o ti tan fun mi, ṣugbọn mo fi ayọ gba a, to si wa a jẹ nnkan ayọ fun mi lonii nitori pe mo duro lori ọrọ ọlọrun ati itan Josẹẹfu. Nigba ti mo de ileeṣẹ ti ẹyin pe ni ilẹ gbigbẹ yi, mo tun un ṣe, mo si sọ ọ di ilẹ ọlọra to n ṣan fun wara ati oyin. Ko si ijọba to n ronu jinlẹ ti yoo fọwọ kere Ayẹyẹ Ilu Ilẹ Afrika, iyẹn African Drum Festival. Adura ni mo n gba nigba ti a ṣe eyi to jẹ akọkọ iru ẹ lọdun 2016, mo kọkọ ro pe Gomina Amosun yoo daa duro pe a ko gbọdọ ṣe e nitori pe ko fọwọ sii. Mo gboya lati sọ ọ nita gbangba faraye pe ko fọwọ sii, ṣugbọn nigba to ri i bi nnkan ṣe n lọ nigba naa, o yi ọkan ẹ pada, eyi lo ṣe jẹ pe fun idi kan to jẹ pe oun nikan lo ye, o gbe gbogbo eto naa kuro nileeṣẹ mi, eyi to ṣe di ọla.

IBEERE: Pupọ ninu awọn nnkan ti ẹ ṣe lo jẹ pe Gomina Amosun ko fiṣẹ ẹ yin yin bo ṣe tọ. Ati pe ṣe ka sọ pe ẹ kabamọ pe ẹ ṣiṣẹ labẹ Gomina Amosun?
AWIKONKO: Rara, mi o kabamọ! Ẹ jẹ ki n lọ nipasẹ ofin. Fifiṣẹ yin eeyan lọna to tọ, ẹ ni lati gbe e yẹ wo nibamu pẹlu ofin adehun. Pe wọn fiṣẹ yin yin naa fẹẹ fara pẹ ẹ. Bi ẹ ba n sọ nipa wipe boya wọn ko fiṣẹ yin mi lori ọrọ olowo de, o ṣee ṣe ko jẹ bẹẹ. Ṣugbọn bi awọn to wa nita ati kaakiri agbaye ba n gbe oṣuba kare fun un, ẹ maa ni ifọkanbalẹ, ẹ maa gbagbọ daadaa, eyi gan an ti to oriyin lọtọ.
 
IBEERE: Fun igba akọkọ, wipe ẹ mu ọpọ awọn orileede wa papọ, bawo ni iriri naa ṣe ri fun un yin?
AWIKONKO: Iyi nla gidi ni, o si fọkan mi balẹ pupọ, to si tun bu iyi ati ọla fun orukọ mi. Eto ta a ṣagbekalẹ ẹ laarin oṣu mẹrin pere ni lai lọwọ ijọba ipinlẹ Ogun ninu. Mo ni igboya lati sọ bẹẹ. Awọn ẹlẹyinju aanu lawujọ ni wọn ṣagbatẹru eto naa. A ko le kọ itan Ayẹyẹ ọdun Ilu Ilẹ Afrika naa lai dupẹ lọwọ Ọlọrun, ka si gbe oṣuba kare fun awọn ileeṣẹ kọọkan atawọn eeyan pataki-pataki, nitori pe nigba ti ijọba to wa nibẹ lọwọ yi ri i pe eto naa ko le so eso rere, Ọlọrun gbe ogo ẹ dide. Mo bẹrẹ eto naa lai lọwọ ijọba ninu, ti mo si ri i bẹẹ titi dasiko yi. Ijọba ko yẹ ko da si nnkan to ba ni i ṣe pẹlu ọrọ irin ajo afẹ rara, wọn ko gbọdọ fi owo ṣagbatẹru eto naa, wọn kan gbọdọ pese aaye ti yoo mu irọrun bawọn eeyan, ki wọn si gbe igbimọ ti yoo ran eto naa lọwọ dide, ki eto iṣuna naa si wa latọdọ awọn araalu.

Nnkan ta a ṣe lọdun 2016 ni pe, mo pe awọn ti wọn n ba mi ṣiṣẹ dide, a si fori-kori lori ọna ti a fẹ ẹ gbe e gba, ti mo si jẹ ko ye wọn pe wọn ko gbọdọ jẹ kijọba lọwọ si i, ṣugbọn ijọba yoo pese aye irọrun fawọn eeyan. A rasnṣẹ pe awọn eeyan ati ileeṣẹ kọọkan ti a mọ, ti wọn si jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun, gbogbo wọn ni wọn si ri ọjọ iwaju rere ninu agbekalẹ wa. Ẹ jẹ ki n dupẹ lọwọ Sir Kessington Adebutu, alaṣẹ Premier Lotto; awọn alaṣẹ ileeṣẹ Bet9ja; Manal Nigeria Limited to wa ni Arepo; tunba ubomi Balogun; Nigerian Breweries; Airtel; Tunde Lm; ba Adedap Tjuoo; atawọn igbimọ lọba-lọba kaakiri ipinlẹ Ogun ni wọn ṣe gudugudu meje ati yaya mẹfa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI