KI LẸ RANTI NIPA OLOOGBE GBENGA ADEBOYE, FUNWỌNTAN?? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 30, 2019

KI LẸ RANTI NIPA OLOOGBE GBENGA ADEBOYE, FUNWỌNTAN??

Bọya lẹ mọ pe oni, ọgbọn ọjọ oṣu kẹrin ọdun 2019 lo pe ọdun mẹrindinlogun ti gbajugbaja sọrọsọrọ nni, ẹni tawọn sọrọsọrọ onii n wo gẹgẹ bi awokọṣe, Oloogbe Elijah Oluwagbemiga Adeboye, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si: Alaaji-Pasitọ-Oluwo, Abẹfẹ, Jengbetiele, Itu Baba-Ita, Alaye mi Gbengulo dagbere faye pe o digboṣe.
Kò sí àníàní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò lé gbàgbé ádẹ́rìnposónu sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ náà nítori àwọn iṣẹ́ to ti gbése kí ó to gbà fún ikú lọgbọ̀n ọjọ oṣù kẹrin, ọdún 2003.

Lárá àwọn iṣẹ́ ti Gbenga Adeboye ti ṣe ni Ọmọ Majẹmu, Ọrọ Ṣunukun 1&2, Ph.D Beetle, Fúnwọntán 1&2, Ọrọ láti orí ìtẹ́ mímọ 1&2, Versatility, Aiyetoto, Controversy, Supremacy, Ijinlẹ, Laisi Abesupinlẹ atawọn min in ta a ko ranti dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

AWIKONKO n fi asiko yi ṣe iranti akọni, ti ko le ku lailai naa, nitori pe iṣẹju-iṣẹju lo fi lọkan gbogbo eeyan, ti wọn mọn-ọn, atawọn ti ko rii ri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI