NITORI SẸNETỌ ADELEKE, WỌN GBE ILEEṢẸ ỌLỌPAA LỌ SILE ẸJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 30, 2019

NITORI SẸNETỌ ADELEKE, WỌN GBE ILEEṢẸ ỌLỌPAA LỌ SILE ẸJỌ

Arabinrin Rofiat Ọladepo ati Abdullahi Oladepo ti wọn jẹ iyawo ati ọmọ akọwe agba ileewe girama Ẹdẹ Muslim Grammar School ni ilu Ẹdẹ, ipinlẹ Ọṣun ti gbe ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria lọ si ile ẹjọ lori ẹsun fifi ipa gbe ni si atimọle lọna aitọ.

Ni ọjọ aje ni wọn pẹjọ naa ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun eyi to fi ikalẹ si ilu Ikirun.

Lara awọn ti wọn tun so pọ mọ ẹjọ naa ni ọga agba ọlọpaa lẹkun kọkanla, AIG Zone XI, ajọ ileeṣẹ ọlọpaa ati amofin agba orilẹede Naijiria, Abubakar Malami lori ifidimulẹ ẹtọ wọn labẹ ofin.

Bakan naa ni wọn tun beere fun biliọnu kan naira gẹgẹ bii owo gba maa binu lori ẹsun fifi ipa muni lai tẹle ilana ofin, fifini si ahamọ ati ifiya jẹni lọna aitọ.

Ni aipẹ yii ni iroyin gbee jade pe awọn ọlọpaa mu awọn olupẹjọ naa si ahamọ lori ẹsun pe baale wọn, to jẹ akọwe agba fun ileewe girama naa ṣe fun sẹnetọ Ademọla Adeleke ni iwe ẹri akẹkọjade ileewe naa.

Awọn ọlọpaa n wadii Sẹnetọ Ademọla Adeleke, oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọṣun ninu idibo gomina ọdun to kọja lori ẹsun ayederu iwe ẹri girama lọwọlọwọ.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI