LẸ́YÌN OṢÙ MÁRÙN ÚN, BUHARI KỌ̀ LÁTI YỌ ỌGA NHIS BÍ ÌGBÌMỌ̀ ṢE SỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 16, 2019

LẸ́YÌN OṢÙ MÁRÙN ÚN, BUHARI KỌ̀ LÁTI YỌ ỌGA NHIS BÍ ÌGBÌMỌ̀ ṢE SỌ

Lẹ́yin oṣu karun un ti igbimọ kan ti ijọba apapọ gbe dide lati wadii ẹsun aṣemaṣe ati jẹgudujẹra ti wọn fi kan ọga ajọ NHIS Usman Yusuf Usman Yusuf, Aarẹ Muhammadu Buhari ko ti i gbe igbesẹ lori abajade iwadii igbimọ naa.

Igbimọ naa sọ ninu abajade rẹ pe ki ileeṣẹ aarẹ yọ akọwe agba ajọ adojutofo ilera Naijiria (NHIS) naa nipo.

Ṣugbọn iroyin fihan pe aarẹ ko ti i gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Yusuf bo ti lẹ ni pe ko lọ simi diẹ nigba ti wọn gbe igbimọ naa kalẹ ni oṣu kẹwaa, ọdun 2019.

Iroyin fihan pe abajade naa ti tẹ aarẹ lọwọ lati oṣu kejila, ọdun 2018.

Abajade naa jade lẹyin oṣu keji ti ijọba apapọ gbe igbimọ ẹleni meje naa dide.

Igbimọ naa ni Yusuf ru ofin to n ṣe akoso bi wọn ṣe n gbe iṣẹ jade labẹ ijọba ati ofin to n dari ileeṣẹ ijọba.

Aarin Yusuf ati Minisita fun Eto Ilera, Ọjọgbọn Isaac Adewole ko wọ lẹyin ti minisita ni ko lọ rọkun nile lori ẹsun jẹgudujẹra owo to din diẹ ni biliọnu kan naira ti wọn fi kan Yusuf.

Ni kete lẹyin rẹ ni ileeṣẹ aarẹ da a pada sipo.

Eyi mu ki ọpọ eeyan maa bere pe ki gan an lo wa laarin aarẹ ati ọjọgbọn Usman Yusuf?

Nigba naa lọun, Ọjọgbọn Yusuf ni ko si ohun ikọkọ kan laarin ohun ati aarẹ ati pe ilana ofin ni aarẹ n tẹlẹ eleyi to fidi rẹ mulẹ wi pe igbimọ tabi minisita ko lee yọ oun bi ko ṣe aarẹ.

Ọjọgbọn Usman Yusuf ni awọn eeyan ti wọn n lo owo ara ilu lati lu jibiti lẹka naa ni wọn n fin ina mọ oun nidi.

Lẹyin rẹ ni igbimọ to n ṣe akoso ajọ NHIS tun ni ki Yusuf lọ rọkun nilẹ.

Ni bayii, igbimọ ti ijọba apapọ gbe dide ti ni ki gbogbo ọmọ igbimọ alakoso NHIS naa maa lọ ile wọn.

Gbogbo igbiyanju ile iṣẹ BBC lati ba ijọba sọrọ lori koko yii ni ko tii bi eso to yẹ.

- BBC YORUBA

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI