NIBI TI ADEWỌLE TI N GBIYANJU LATI JA ỌKADA GBA LỌWỌ ỌLỌPAA TI TẸ Ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 29, 2019

NIBI TI ADEWỌLE TI N GBIYANJU LATI JA ỌKADA GBA LỌWỌ ỌLỌPAA TI TẸ Ẹ

“Ẹ foju aanu wo mi” lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n tẹnu ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn kan, Ṣeun Adewọle jade titi dasiko ti ẹ n ka iroyin yi, iyẹn lọgba ọlọpaa SARS to wa ni Magbọn niluu Abẹokuta.

Kii ṣe pe ọwọ ọlọpaa dee de tẹ Adewọle, bi ko ṣe pe awọn ara agbegbe Adiyan niluu Agbara lo rọwọ to Adewọle lasiko toun atawọn ọrẹ ẹ jọ n gbiyanju lati ja ọkada gba, ti wọn si lọọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.

Ni nnkan bi aago meje aabọ aarọ ọjọ naa la gbọ pe ọwọ tẹ ẹ, tawọn ẹmẹwa aẹ si na papa bora.

AWIKONKO gbọ pe ibọn ilewọ kekere kan, ada alaamu ati oogun oriṣiriṣi ni wọn gba lọwọ ẹ.

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ọgba SARS ni Adewọle wa to ti n gbatẹgun lẹyin ti Kọmiṣana ọlọpaa ti paṣẹ pe ki wọn maa muu lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI