ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ RASAKI, OPEYẸMI, KABIRA ATI SAHEED TO N TA IGBO L’AGBARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 29, 2019

ỌWỌ ỌLỌPAA TẸ RASAKI, OPEYẸMI, KABIRA ATI SAHEED TO N TA IGBO L’AGBARA

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ọgba ọlọpaa FSARS to wa ni Magbọn niluu Abẹokuta lawọn mẹrin kan ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju igbo tita lọ wa, ti wọn ti n gbatẹgun igbalode tawọn ọdaran.

Ọjọ Satide Abamẹta to kọja lọ yi lọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ wọn lagbegbe kan ti wọn n pe ni Iperin Black Spot, Agbara pẹlu ẹrọ to n mu omi tutu, iyẹn Firiiji (Fridge), eyi ti wọn sọ pe igbo ni wọn fi n ta, kii ṣe omi tabi ọti ẹlẹrindodo.

Awọn mẹrin naa ni Ọpẹyẹmi Wahab, ẹni ọdun mejilelogun; Kabirat Ahmed, ẹni ọdun mọkalelogun; Yusuf Rasaki, ọmọ ogun ọdun ati Saheed Mustapha toun jẹ agbalagba laarin wọn, ẹni ọdun mẹtadinlogoji loun jẹ.

AWIKONKO gbọ pe o ti le lọdun marun tawọn eeyan yi ti n ta igbo naa, tawọn to wa lagbegbe naa si mọ wọn daadaa, ko da, ti wọn tun sọ pe gbajugbaja ni wọn laarin awọn onibaraa wọn lagbegbe naa.

Awọn ara agbegbe naa ti wọn lọrọ awọn ọdaran yi ti su wọn ni wọn lọọ ta awọn ọlọpaa lolobo, ti wọn si gbe igbesẹ lati lọọ ko wọn. Bi wọn ṣe debẹ la gbọ pe ṣe lo ya gbogbo awọn eeyan lẹnu nigba tawọn ọlọpaa ṣi firiiji ti wọn ba nikawọ wọn wo, to si jẹ pe igbo lo kun inu ẹ.

Lara awọn to fiṣẹlẹ naa to wa leti jẹ ko ye wa pe, ṣe ni wọn n lo firisa naa lati fi tan awọn eeyan jẹ pe omi tutu ati ọti tutu ni wọn fi n ta, ayafi igba tawọn ọlọpaa tu aṣiri wọn.

Nigba ti wọn n jẹwọ ẹṣẹ wọn, gbogbo wọn ni wọn sọ pe ogbontarigi lawọn ninu iṣẹ naa.

Ni bayii, Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Bashir Makama ti paṣẹ pe ki wọn tubọ lọọ ṣewadi awọn ọdaran naa daadaa, ki wọn rii daju pe ọwọ tẹ awọn ti wọn n ta a fun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI