NIBI TI ṢEUN TI FẸẸ JA ỌKADA GBA LỌWỌ TI TẸ Ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 22, 2019

NIBI TI ṢEUN TI FẸẸ JA ỌKADA GBA LỌWỌ TI TẸ Ẹ

Igbe ‘temi ba mi’lo n tẹnu ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26) kan, Ṣeun Adewọle nigba tọwọ tẹ ẹ lasiko ti wọn lo n gbiyanju lati ja ọkada gba lọwọ ẹni to ni i, iyẹn lagbegbe Adiyan, Agbado, ipinlẹ Ogun.
 
Ni nnkan bi aago meje aabọ aarọ ọjọ Sande ana la gbọ pe Ṣeun ati ọrẹ ẹ ti wọn pe ni Ojo Ibẹru ti wọn jọ wa ninu ẹgbẹ okunkun Aye la gbọ pe wọn da ọlọkada kan duro, nibi tiyẹn si ti fẹẹ gbe wọn ni wọn ti yọ ibọn si i.

Ariwo ti wọn ni ọlọkada naa pa lo mu kawọn ara agbegbe naa sare debẹ, ti ọwọ si tẹ Ṣeun, ṣugbọn to ṣeni laanu pe ekeji ẹ, Ojo raaye na papa bora.

Awọn ara adugbo naa la gbọ pe wọn mu Ṣeun lọ teṣan ọlọpaa ẹkun Agbado, nibẹ lo si ti jẹwọ fun wọn pe iṣẹ adigunjale loun fi n jẹun.

Ni bayii, Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Baṣhir Makama ti paṣẹ pe kawọn ọlọpaa SARS mu Ṣeun lọọ jẹ igbadun diẹ lọdọ wọn, ko too di pe wọn foju ẹ bale ẹjọ, bẹẹ lo sọ pe ki wọn gbiyanju lati ri Ojo to na papa bora naa mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI