NITORI PỌNMỌ OLORO, IYALE ILE MẸTA WỌ GAU L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 29, 2019

NITORI PỌNMỌ OLORO, IYALE ILE MẸTA WỌ GAU L'EKOO

Gbogbo ẹyin ti ẹ fẹran lati maa yi pọnmọ lata, ikilọ re e lori awọn pọnmọ oro kan to wa nita bayii.

Ijọba ipinlẹ Eko lo fi ikilọ sita fun awọn ara ilu pe ki wọn ṣọra lati maa jẹ awọn pọnmọ oloro kan to wa lọja bayii.

Ijọba naa ni awọn ti mu eeyan mẹta ti wọn n ta awọn pọnmọ yii ni ijọba ibilẹ Ọjọ ati Iba ti wọn si tun ko awọn pọnmọ oloro wọnyii lori igba wọn.

Ninu atẹjade kan ti Kọmisana eto ilera nipinlẹ naa Dokita Jide Idris fi sita, ijọba ipinlẹ Eko lawọn ti ''ko awọn eeyan mẹta ti ọwọ tẹ lori pọnmọ oloro yii lọ si iwaju ile ẹjọ ti awọn si ti fi awọn pọnmọ naa ranṣẹ si ile ayẹwọ ile iṣẹ NAFDAC ti yoo sọ boya wọn ṣee jẹ''

Idris salaye ninu atẹjade naa pe ijọba bẹrẹ si ni tojubọ ọrọ pọnmọ oloro yi lẹyin igba ti awọn kẹfin pe awọn kan n ta pọnmọ ni ago mẹrin si ago mẹfa aarọ lawọn aaye kan ni Ọjọ ati Iba.

O wa kilọ f'aralu pe ki wọn ṣe ayẹwo daada ki wọn to ra pọnmọ lọja ki wọn si tete ta awọn oṣiṣẹ ijọba lolobo bi wọn ba funra si awọn ounjẹ kankan ti o ni kọnunkọhọ.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI