ỌBASANJỌ ATI BUHARI DERO ATIMOLE ỌLỌPAA, IGBO NI WỌN N TA L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 29, 2019

ỌBASANJỌ ATI BUHARI DERO ATIMOLE ỌLỌPAA, IGBO NI WỌN N TA L'EKOO

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, tesan ọlọpaa Okoko niluu Eko ni awọn ọdọmọkunrin meji kan, Ṣẹgun Ọbasanjọ, ẹni odun mẹtadinlogoji (37)  ati Buhari Oseni, ọmọdun mẹtadinlọgbọn wa, ti wọn n bẹbẹ fun idariji ẹṣẹ wọn.

Ọsan ọjọ Satide Abamẹta to kọja la gbi pe ọwọ ọlọpaa tẹ Ṣẹgun atawona ẹmẹwa rẹ mẹrin min-in ti wọn ni wọn kò niṣẹ meji ju igbo tita lọ, inu ọja Alaba Rago l'Eko gan an ni wọn ti n ta fawon onibara wọn.

Awọn mẹrin tọwọ tun tẹ ni Job Omesi, ọmọdun mẹrindilogun (16); Ayomide Samuel, ọmọdun mọkanlelogun (21); Muda Haruna, ọmọ ọgbọn ọdun (30); ati Suraju Ayuba toun jẹ ọmọdun mejidinlogbon (28).

Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana lo firoyin naa sita lọjọ Sande ana.

Wọn ni ọna tawọn ọdaran yi n gba ta igbo wọn lodi sofin, to si tun n ko irira b'awọn ara agbegbe naa.

Yatọ s'awọn ọdaran yi, a gbọ pe ọwọ ti tẹ awọn mẹfa kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun lọjọ kẹrinla oṣu yi ni nnkan bi aago mẹwaa aabọ aarọ. Ọwọ tẹ awọn eeyan naa ti wọn lawọn lo ṣokunfa iku awọn mẹfa kan lagbegbe Ajah lọjọ naa.

Awọn mẹfa naa ni Babatunde Wasiu, ẹni ọgbọn ọdun (30); Bolaji Elijah, ọmọdun marundinlogbon (25); Joseph Timothy, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32); Bolaji Ọlayiwọla, ọmọdun mejilelogun (22); Saheed Lateef, ọmọdun mejilelogun (22) ati Julius Augele, toun jẹ ọmọ ogun ọdun (20).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI