ỌWỌ FIJILANTE TẸ ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN MẸRINLA N'IPOKIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 30, 2019

ỌWỌ FIJILANTE TẸ ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN MẸRINLA N'IPOKIA

Kani kii ṣe pe gbogbo igba lawọn oṣiṣẹ fijilante tipinlẹ Ogun, VSO fi n ṣiṣẹ aabo ni, bo ya aṣiri awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn tun n digunjale tọwọ wọn tẹ laipẹ yi ko ba ti ma tẹ wọn.

Ọjọ Sande to kọja yi lọwọ tẹ wọn ni nnkan bi aago mẹfa aarọ lagbegbe Ibatẹfin, ijọba ibilẹ Ipokia, nipinlẹ Ogun.

Awọn ọdaran naa ni; Abu Fatai, ọmọ ogun ọdun; Salami  Razaq, ọmọdun mẹtalelogun; Wọnṣebọlatan, ọmọdun mọkanlelogun; Babatunde Samson, ọmọdun mọkanlelogun; Ọlaotan Ọlayinka, ọmọdun mejilelogun; Kọla Adebayọ, ọmọdun mejilelogoji; Koju Afọṣẹ, ọmọdun mọkandinlogun;

Bamigbade Adekanbi, ọmọdun mọkanlelogun; Agbabu Wasiu, ọmọdun mọkanlelogun; Babatunde Ṣẹgun, ọmọ ogun ọdun; Ọlawunmi Abel, ọmọdun mọkanlelogun; Ọlamlekan Ahmed, ọmọdun mọkanlelogun; Abiọdun Mose Akanmu, ọmọdun mẹtalelogun ati Ganiu Taiwo.

Agbenusọ fun ẹgbẹ fijilante nipinlẹ Ogun, Mọruf fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si lawọn ti fa awọn ọdaran naa le awọn ọlọpaa lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI