Bọsun Ọlaniyi Abẹokuta: Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yi ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe afaimọ ko ma jẹ pe inu airoju-raaye ni ijọba tuntun ti Ọmọba Dapọ Abiọdun to n bọ yi ma ti ṣe saa rẹ, iyẹn bi ko ba tẹtẹ gbe igbesẹ to yẹ lati ṣe atunṣe to ba yẹ lori igbimọ ti yoo jiroro nipa ijọba ẹ ati ọrọ aje ipinlẹ Ogun to yan naa bẹrẹ lati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun ọdun yi.
Ohun ta a gbọ ni pe, awọn ara agbegbe kan nijọba ibilẹ Ogun Waterside ni wọn fi ẹhonu wọn han sita lori igbimọ naa, latari bi wọn ko ṣe fi eeyan kankan nijọba ibilẹ wọn, paapaa lawọn wọọdu meji kan ti wọn pe ni Ayede/Lomiro ati Ayila/Itebu.
AWIKONKO gbọ pe awọn wọọdu meji yi lo jẹ pe awọn Ikalẹ ati Alajẹ ni wọn tẹdo sibẹ, to si jẹ pe awọn gan an ni wọn n mu idagbasoke ba awọn agbegbe yii, paapaa bi wọn tun ṣe sọ pe awọn naa ni wọn gba awọn eeyan la lasiko ojo.
Ninu lẹta kan ti wọn kọ ranṣẹ si Gomina tuntun to n bọ naa, Ọmọba Dapọ Abiọdun, eyi ti agbẹnusọ ati akọwe ipolongo fawọn agbegbe naa, Kọmureedi Oyinbo Adelẹyẹ Fẹstus ati Ọmọba Adenẹgan Ẹnigbọkan bu ọwọ lu, eyi ti ẹda ẹ tẹ AWIKONKO lọwọ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe afi ki Ọmọba dapọ Abiọdun tete wa nnkan ṣe si ọrọ igbimọ ijiroro naa, nitori tawọn ko gba a wọle rara.
Wọn ni ṣe lo dabi i pe tori awọn ko pọ lagbegbe naa lo mu ki wọn fẹẹ fi ẹtọ wọn dun wọn, to si jẹ pe pẹlu igbesẹ ti wọn fi yan awọn igbimọ naa, bi i pe wọn fẹẹ gba ẹlẹyamẹya laaye ninu ijọba naa ni, tawọn si gbọdọ tete sọrọ jade ko to o pẹ ju.
Ninu lẹta naa ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ijọba ibilẹ Ogun Waterside to ni wọọdu mẹwa lo jẹ pe oriṣiriṣi ẹya ni wọn tẹdo sibẹ, ti wọn si n gbe agbegbe naa, ati pe nigba ti Ọmọba dapọ Abiọdun n ṣeleri fawọn eeyan lasiko ipolongo, ohun pataki to sọ ni pe oun yoo jẹ ki oṣelu naa kari lai yọ ẹya kankan sọtọ.
A gbọ pe ki Ọmọba Dapọ Abiọdun to o fidi igbimo naa lelẹ lọsẹ to kọja yi, aimọye igba ni wọn ti pe e sakiyesi pe ko tete ṣatunṣe, ṣugbọn ti wọn ni ko dahun.
Wọn wa a sọ pe pẹlu igbesẹ nipa igbimo ijiroro tuntun naa, awọn ti ri i ninu iwe ofin to de igbimọ naa jẹ eyi ti wọn fi ẹlẹyamẹya ṣe.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn wọọdu naa ni wọn pe ni; Efirẹ, Oni/Alọ, Ayede/Lomiro, Ibiade, Ayila/Itebu, Lukogbe/Iluṣin, Makun/Irokun, Abigi, Ode-Omi la gbọ awọn ẹya nla meji, iyẹn awọn Ikalẹ ati Ilajẹ ni wọn pọ ju nibẹ, ti wọn si n ran awọn eeyan lọwọ lọna to pọ.
Yatọ si eyi, a gbọ pe awọn Ijẹbu naa wa ti wọn gbe agbegbe yi, to si jẹ pe gbogbo ipo ti wọn pin sagbegbe naa, awọn Ijẹbu nikan ni wọn pin in fun, ti wọn si yọ awọn to ṣe pataki nibẹ sẹyin, ti wọn si n rọ Ọmọba Dapọ Abiọdun lati tete yi igbesẹ naa pada, ko si fi wọn si i, nitori pe kii ṣe awọn Ijẹbu nikan ni wọn gbe agbegbe naa.
Wọn ni ipinlẹ Ogun ki i ṣe ti ẹya kan, bi ko ṣe ti gbogbo eeyan nitori naa ni wọn ko ṣe gbọdọ yọ awọn apakan sọtọ, tabi pe ki wọn le wọn sẹyin. Bẹẹ ni wọn tun sọ pe o kere ju, wọn gbọdọ fi aaye meji silẹ fawọn ẹya meji yi lati wa nibẹ ninu igbimọ ijiroro naa, eyi ti yoo jẹ kawọn araalu mọ pe looto ni fun gbogbo eeyan laaye lati kopa ninu ijọba tuntun naa.
Ni bayii, ohun ta a gbọ ni pe awọn eeyan naa ti sọ pe awọn ko ni gba, ayafi ti atunṣe to tọ ba wa.
No comments:
Post a Comment