NITORI MI O GBỌ IPE AṢIWAJU TINUBU NI KỌMIṢANA ỌLỌPAA IPINLẸ EKO ṢE TI MI MỌLE FUN OṢU KAN - ỌMỌBA ADEDIPẸ DAUDA EWENLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 20, 2019

NITORI MI O GBỌ IPE AṢIWAJU TINUBU NI KỌMIṢANA ỌLỌPAA IPINLẸ EKO ṢE TI MI MỌLE FUN OṢU KAN - ỌMỌBA ADEDIPẸ DAUDA EWENLA

Ọlaide Ọṣinuga, Eko: Ọkan lara awọn oludije sipo ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko, Ọnọrebu Adedipẹ Dauda Ewenla to fẹẹ ṣoju awọn ara agbegbe Alimọṣọ Constituency 1 ninu eto idibo to kọja yi, ṣugbọn ti ko pada lanfaani lati ṣe ipolongo, lẹyin to gba fọọmu labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe ilokulo ni ẹgbẹ oṣelu APC n lo Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Eko, Edgar Imohimi.

Ọnọrebu Adedipẹ Dauda Ewenla to tun jẹ Ọmọba, eni to jẹ oludasilẹ Adedas Foundation lo ṣalaye ọrọ yi f'AWIKONKO laipẹ yi niluu Eko nigba to n sọ iriri ati ipenija to ba pade nidi oṣelu, paapaa ti eto idibo to kọja lọ laipẹ yi.

Ọmọ bibi Abule Ẹgba naa sọ pe oun ko tii ṣalabapade iru ipenija nla bayii ri, nitori pe ṣe ni ẹgbẹ oṣelu APC ledi apo pọ pẹlu Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Eko lati ma jẹ koun gbegba oroke ninu eto idibo to kọja yi, to si ni laipẹ, oun yoo gbe igbesẹ to ba tọ.

Wọnyii ni ẹkunrẹrẹ nnkan ti Ọmọba Dauda Ewenla ba Ọlaide Ọṣinuga, akọroyin AWIKONKO sọ:

“O ti pẹ ti mo ti wa ninu oṣelu yi latari ironilagbara ti mo maa n ṣe fawọn eeyan, to si jẹ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ni mo ti bẹrẹ. Pato nnkan to mu ki n gbe apoti ni pe mo ri i pe iya to n jẹ awọn ara agbegbe Alimọṣọ ti mo ti wa pọ gidi, ti mo si ri i pe awọn oloṣelu ko ṣetan lati ṣe atunṣe si i. Ọmọ ilu Abule-Ẹgba ni mi, ti mo si tun ni ile ati ọfiisi sibẹ. Bi ẹ ba wo ẹni to n ṣoju wa, ẹ ko le tọka si ọfiisi ẹ ni Alimọṣọ yi bo ṣe tobi to. Boya nnkan kan ṣẹlẹ, ẹ fẹẹ ri i, ẹ ko lemọ ibi ti ẹ ma a wa si i.

“Bakan naa, Sẹnetọ wa, ẹ ko le mọ ọfiisi ti ẹ maa wa a si. Ko si anfaani kan tawọn eeyan le maa ri jẹ lara wọn. Wọn ko ṣe ohunkohun fawọn araalu ti wọn si mọ pe iya nnkan naa n jẹ wọn yi wa ni ikapa wọn. Idi ni yii ti mo fi jade lati lọọ kọ iya naa fun wọn.

“Wẹl, nnkan ti mo le sọ ni pe, mo ri i pe awọn ojuṣe ti o yẹ ki awọn ọlọpaa ṣe lori iwadi wọn ko le kun oju oṣuwọn latari pe awọn to yẹ ki wọn gbe ẹjọ yẹn le lọwọ pe ki wọn ṣe e, wọn kọ lati gbe le wọn lọwọ, nitori pe awọn ti wọn ṣe ẹjọ yẹn, nnkan ti ijọba da wọn silẹ fun ni pe ki wọn ṣiṣẹ lori ẹsun ijamba ole., ṣugbọn ti wọn lo o ṣẹlẹ ti wọn fi gbe mi, ọrọ wi pe wọn bẹ ọpa epo ni. Awọn kan wa tijọba ya sọtọ to yẹ ki wọn ṣiṣẹ lori wi pe awọn kan ji epo wa, iyẹn awọn ti wọn n pe ni anti-vandal, ṣugbọn wọn kuna lati gbe iṣẹ naa le wọn lọwọ latari idi kan ni pato to ye wọn.

“Maa kuku sọ pe wọn gbabọdi latari apoti aṣelu ti mo gbe lati lọọ ṣoju awọn eeyan mi ni Alimọṣọ, ẹkun kinni in (Alimọṣọ, constituency 1) nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko. Bi wọn ko ba gbabọdi ni, ko si nnkan to le jẹ ki wọn maa pariwo pe awọn n wa mi. Mo tun yọju si wọn, sibẹ, wọn tun ti mi mọle fun ọjọ mẹtadinlogoji (37days). Nnkan ti mo kọkọ ro tẹlẹ ni pe mboya wọn ni mo wa nibẹ ni, abi awọn kan n darukọ mi mọ wọn ni, ayafi igba ti mo wa a lọ sibẹ lati mọ nnkan ti wọn n wa mi fun un, ti wọn mu aburo ati iyawo mi tori ẹ, bi mo ṣe n de bẹ ni wọn fi wọn silẹ pe emi ni wọn n wa. ọjọ mẹsan an ni wọn fi ti iyawo mi mọle. Igba ti mo de bẹ, wọn gba ọrọ ẹnu mi silẹ, lẹsẹkẹsẹ ni wọn sọ pe ki wọn lọọ ti mi mọle. Gbogbo awọn ti wọn mu, sẹẹli ọtọọtọ ni wọn fi wa si, a ko ri ara wa ba sọrọ.

“Ọjọ keji ni wọn pe wa pe ọga awọn saasi, iyẹn OC SARC tii ṣe Peter Gana fẹẹ ba wa ni gbolohun, igba ti wọn ko gbogbo wa jade la bẹrẹ sii ri oju ara wa, mo ri awọn ti mo mọ, mo si ri awọn ti mi o mọ rara. Ọlọpaa to ṣe ẹjọ yẹn ni wọn n pe ni Ayọdele Michael Ogbeṣigidi, oun lo gbe iwe dani to n ka nnkan ti onikaluku wa kọ silẹ lẹyọkọọkan niwaju Peter Gana. Bo ṣe n ka awọn ẹsun yẹn ni lo ṣa n ya mi lẹnu pe ko si eyi to jọmọ temi nibẹ, ko sẹni to darukọ mi. Igba to ka awọn ẹsun naa tan, ni OC SARS tun beere lọwọ gbogbo wọn pe ṣe wọn mọ mi, awọn meji kan ti mi o mọ ri sọ pe awọn ko mọ mi ri, awọn yooku, mi o le sọ pe mi o mọ wọn ladugbo nitori pe oloṣelu ni mi, mo si tun ni ajọ iranlọwọ kan ti mo n ṣe lati ran awọn eeyan lọwọ, nitori naa lara awọn to ti jẹ anfaani lara ajọ yi naa wa nibẹ, ti wọn si tun maa n wa si eto idanilẹkọọ itunu aawẹ ti mo maa n ṣe.

“Awọn kan naa si wa to jẹ pe oṣiṣẹ mi ni wọn. Awọn to ṣiṣẹ yẹn jẹwọ pe lootọ, awọn lawọn ṣe ẹ,pe emi ko mọ nnkankan nipa ẹ. Bi wọn ṣe n sọrọ, wọn n jẹ ko wọn pe awọn ọlọpaa lo wa a fi sẹkẹṣẹkẹ ko awọn pe awọn fẹẹ ṣiṣẹ kan ladugbo yẹn, pe ti wọn ba sọrọ, awọn yoo pa wọn danu. Gbogbo ọrọ ti wọn ṣa n sọ ni mi o ri eyi to jẹ temi nibẹ. Igba ti OC SARS n beere nnkan ti mo mọ nipa ẹ, mo sọ pe mi o mọ nnkan kan nipa ẹ, ati pe iru nnkan bẹẹ ti ṣẹlẹ ri lọdun 2006 to jẹ pe ọpọ ẹmi lo sọnu, latigba yẹn lawọn ọlọpaa ti ṣọ agbegbe yẹn, awọn oṣiṣẹ sifu difẹnsi wa nibẹ yẹn, ko da, ti wọn tun kọ ọfiisi wọn sibẹ, yatọ si eyi, NNPC gba awọn ẹṣọ to n ṣọ ibẹ yẹn.

“Ọrọ ti wọn n pariwo mi le lori yi, ọga ọlọpaa l’ẹkun yẹn, iyẹn Area Commander ti pe mi lori ẹ ri, ti mo si sọ fun wọn pe ki wọn lọọ ṣeadi awọn kan, nnkan tawọn yẹn ba sọ ni otitọ, nitori pe emi o mọ nnkankan nipa ẹ. Ko si nnkan to le fẹẹ ṣẹlẹ nibẹ yẹn tawọn sifu difẹnsi, awọn ọlọpaa, atawọn oṣiṣẹ aabo tawọn NNPC gba sibẹ wa ti wọn ko ni i mọ nipa ẹ, ti wọn ko si pariwo wọn, to jẹ pe orukọ temi ni wọn n pariwo kaakiri.

“Nnkan to da mi loju ni pe awọn oloṣelu ni wọn n lo awọn to n pariwo mi kaakiri yi, bi ọrọ yẹn ṣe n lọ ti otitọ foju han ni Peter Gana sọ pe ki wọn lọọ tu mi silẹ ki n maa lọ, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe ṣe ni Kọmiṣana ọlọpaa fariga pe mi o le lọ, pe ki gbogbo aye sọ pe mi o mọ nnkankan nipa, oun ko ni i fi mi silẹ lọ. Ori wi pe wọn maa fi mi silẹ la wa ti mo fi lo ọjọ mẹtadinlogoji.

“Igba ti wọn ri i pe idibo ku ọjọ mẹrin pere ni ṣẹṣẹ fi mi silẹ pe ki n maa lọ, wọn ko jẹ ki n raaye ṣe ipolongo idibo, wọn ko jẹ ki n lọọ ri awọn ti yoo ran mi lọwọ fun eto idibo ti gbe apoti ẹ, wọn tun wa sile mi, wọn gbe mọto ti mo fi n ṣe ipolongo kaakiri lọ, iyalẹnu lo jẹ fun mi pe nigba ti wọn ṣe gbogbo awọn iwadii wọn, wọn ri i pe mi o mọ nnkankan nipa ẹ, sibẹ, wọn tun ti mi mọle.

“O ya mi lẹnu pe Kọmiṣana ọlọpaa, Edgar Oluwọle Imohimi le maa purọ fun gbogbo agbaye gẹgẹ bi ipo to di mu, nitori pe ninu iwe ẹsun to fi sọ pe oun n wa mi, o lawọn mẹrin kan toun foju wọn han fawọn araalu lo darukọ mi, pe ki n yọju sawọn, ti mo si lọ, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun mi pe nigba ti mo maa de bẹ, ko ti i sẹni ti wọn foju wọn han. O kan fẹẹ lo ipo ẹ lati ba mi lorukọ jẹ kaakiri agbaye, ko si le raaye jiṣẹ fawọn oloṣelu to ran an niṣẹ.

“Awọn oloṣelu lo lo Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Eko, Edgar Imohimi lodi si mi, lati fi ba mi lorukọ jẹ. Mi o wa mọ boya ẹṣẹ ni lati gbapoti labẹ ẹgbẹ oṣelu alatako nipinlẹ Eko, ṣugbọn nkan ti mo mọ ni pe labẹ ofin, onikaluku lo lẹtọọ lati jade dupo labẹ ẹgbẹ oṣelu yoowu lorileede yi. Mi o mọ nnkan ti Edgar ri, mi o si mọ ẹtọ to ni labẹ ofin nigba tawọn ti wọn mu ti sọ pe mi o mọ nnkan nipa ẹ, to si tun maa yari pe oun ko ni i fi mi silẹ.

“Oriṣiriṣi igbesẹ lawọn eeyan mi gbe nigba ti mo fi wa nibẹ, bo tilẹ jẹ pe mi o mọ iru igbesẹ tonikaluku wọn gbe, oriṣiriṣi iwe ẹsun ni wọn kọ mọ wọn, ti wọn si n pariwo awọn ọlọpaa sita, igba to ya lo tun waa ba mi pe aburo mi kan, Tunde Conel gbe oun lọ sile ẹjọ ati ileeṣẹ to n ja fẹtọ awọn eeyan, ati pe fun idi ẹ, oun ko ni i fi mi silẹ, awọn awawi ti ko lẹsẹ nilẹ lo ṣa n sọ nigba yẹn.

“Lootọ, ki eto idibo to o de, mo ti ni ipenija pẹlu awọn oloṣelu kọọkan, mi o fẹẹ darukọ wọn, ṣugbọn awọn oloṣelu ti mo ni ipenija pẹlu wọn lawọn APC nitori pe ọpọ igba ni wọn wa ba mi pe ki n juwọ silẹ fawọn, wọn wa a ran Ọnọrebu Oloworẹmi Adeyẹmi wa pe ki n wa a darapọ mọ APC, ki n kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, mo ni ko le ṣee ṣe. Igba to tun ya, wọn tun sọ pe awọn yoo fun emi ti awọn eeyan mi ni ọgọfa silọọti (120 slots), pe wọn yo ma a fun wọn ni ẹgbẹrun lọna ogun loṣooṣu, pe ki wọn gba fọọ.

“Igba to tun ya, wọn ni Sẹnetọ Yayi n wa mi, o fẹẹ fun mi ni miliọnu lọna ogun naira, mo si sọ pe mi o nilo owo wọn, ẹtọ awọn ara Alimọṣọ ni mo fẹẹ lọ ja fun. Ko tun pẹ ni wọn ran ọkunrin kan wa pe Aṣiwaju Bọla Tinubu fẹẹ ri mi, mo si ni mi o le lọ nitori pe kii ṣe ọga mi, mo ni Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC ni Tinubu, ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lemi, nitori naa, ko si nnkan ipade ti mo fẹẹ ba Tinubu ṣe. Wahala yẹn ṣi wa nilẹ ti wọn n ba mi fa lọwọ.

“Wọn ti lọọ ba zonal coordinator wa kan, ti wọn sọ fun un pe awọn yo fiya jẹ mi, pe mi o ni i ṣe idibo yẹn nita gbangba, mo si sọ fun wọn pe ko si nnkan to jọ ọ, lagbara Ọlọrun ma a ṣe nita, lai mọ pe wọn ti ni erongba buruku silẹ fun mi. Mo wa a ri nnkan to ṣẹlẹ si mi pe awọn oloṣelu, iyẹn awọn APC ni wọn lẹdi apo pọ pẹlu Kọmiṣana ọlọpaa lati ti mi mọle.

“Igba ti wahala yẹn pọ titi, to di pe wọn ko fi mi silẹ, tawọn eeyan mi si n ba wọn fa, ni wọn fi mi silẹ. Ki i se pe wọn dee de fi mi silẹ, wọn gbe mi lọ sile ẹjọ ni, ile ẹjọ si sọ pe awọn fun mi ni beeli, iyalẹnu lo jẹ pe ṣe lawọn ọlọpaa tun sọ pe awọn ko ni i gba ki wọn gba beeli mi. Adajọ lo ṣa a yari pe gbogbo ẹri toun ri foju han pe mi o mọ nnkankan nipa ẹ, nitori naa, oun ko ri idi kan toun ko ni i fi gba beeli mi.

 Igbeṣẹ to kan

“Mo mọ pe gbogbo nkan to ṣẹlẹ yi, ọwọ Ọlọrun lo wa, fun idi eyi, o dami loju pe ati arọmọdọmọ wọn yoo jẹ ninu iya yi. Mi o ti i ni i sọ igbeṣẹ ti mo fẹẹ gbe fun oniroyin tabi ẹnikẹni lasiko yi, ṣugbọn mo mọ daju pe Ọlọrun yoo kọ mi mọ ọn ṣe.

“Mo fẹ kawọn araalu mọ pe gbogbo nnkan to ṣẹlẹ yi, ọrọ oṣelu ni, mo si fẹ ki wọn mọ pe awọn oloṣelu, iyẹn APC lo lẹdi apo pọ pẹlu awọn ọlọpaa lati ṣiṣẹ lodi si mi, nitori pe wọn ri i pe awọn ko lero lẹyin to mi, idi ni yi ti wọn fi wo o pe ọna wo lawọn le gba lati ma jẹ ki n ri ipo naa gba, ni wọn fi ṣe bẹẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI