ONIJẸKUJẸ LAWỌN OLOṢELU TO N LỌ ṢEPADE LOKE OKUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 27, 2019

ONIJẸKUJẸ LAWỌN OLOṢELU TO N LỌ ṢEPADE LOKE OKUN

Ajafẹtọ ọmọniyan, Ọmọlolu Akinwale ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ awọn adari ni Naijiria ti wọn ma n lọ si oke okun lati lọ ṣe ipade ṣaaju idibo lorilẹede Naijiria.

Ọmọlolu bu ẹnu atẹ lu iṣesi yii lasiko to n ba BBC sọrọ lori bi oludije fun ipo adari Ile Igbimọ Asojusofin, Femi Gbajabiamila ko aṣojuṣofin aadọta ti wọn sẹsẹ dibo yan lọ si Saudi Arabia lati lọ sepade.

Iroyin gbe e jade pe adari ẹsin musulumi ni ariwa Naijiria, Sheikh Dahiru Usman to wa pẹlu awọn aadọta asojusofin ti wọn dibo yan naa ti buwọlu Gbajabiamila gẹgẹ bi ẹni ti yoo jẹ adari Ile Asojusofin lorilẹede Naijiria.

Ajafẹtọ ọmọniyan naa ni ohun to buru jai ni ki wọn fi owo to yẹ ki wọn fi tun ilu se, lọ maa fi se ipade ti wọn ṣi wà lori alefa. Ati wi pe o jẹ ọna ati ko owo jẹ ati lati se owo ilu basubasu.

O fi kun un wi pe o yẹ ki Aarẹ Buhari to n gbogun ti iwa ibajẹ kan an ni dandan wi pe, ko gbọdọ si ẹni ti yoo lọ si oke okun lati lọ se ipade ni okeere.

Ọmololu Akinwale naa wa fi kun wi pe ko si ipade kankan ti eniyan fẹ se ti ko le e se ni awọn ilu to lamilaaka lorilẹede Naijiria, ti yoo si yori si rere.  

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI