OWOLABI AJASA, GOMINA TAMPAN NIPINLẸ OGUN YAN GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ GẸGẸ BI AMUGBALẸGBẸ LORI ỌRỌ IROYIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 23, 2019

OWOLABI AJASA, GOMINA TAMPAN NIPINLẸ OGUN YAN GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ GẸGẸ BI AMUGBALẸGBẸ LORI ỌRỌ IROYIN

Laipẹ yi ni awuyewuye kan jade sita pe Gomina ẹgbẹ oṣere taita nipinlẹ Ogun, Kọmureedi Owolabi Ajasa yan ọkan lara awọn gbajumọ sọrọsọrọ tawọn eeyan n gba tiẹ lasiko yi, Ọgbẹni Ayọbami Akanji Adelani tọpọ awọn eeyan mọ si Ọba Pedepede gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ lori ọrọ iroyin ati bo ṣe n lọ, iyẹn Special Assitant on Media fun ẹgbẹ oṣere TAMPAN

“Irọ ni, ahesọ lasan ni, ko le ri bẹẹ” lọrọ to n tẹnu pupọ ninu awọn ti ọrọ naa ta si etigbọ wọn jade, ṣugbọn ti AWIKONKO wa a pada fidi ẹ mulẹ pe otitọ pọnbele ni.

Ohun ta a gbọ ni pe ko si nnkan meji to mu ki Gomina ti wọn dibo yan ni nnkan bi oṣu mẹfa sẹyin ninu ẹgbẹ oṣere naa, Owolabi Ajasa yan Ọba Pedepede gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ bi ko ṣe ti ipa to ti ko lawujọ amuludun, paapaa bo tun ṣe ṣagbatẹru ẹ lasiko ti ipolongo n lọ lọwọ, ati lẹyin idibo.

Awọn to kọkọ gbe ọrọ naa si wa leti jẹ ko ye wa pe ọpọ igba ni Ọba Pedepede ti lo awọn nnkan ini ẹ fun aṣeyọri Kọmureedi Ajasa lati ri i pe ipo naa ja mọ ọn lọwọ, to si pada ri bẹẹ.

AWIKONKO gbiyanju lati ba Ọba Pedepede sọrọ lati fidi ahesọ naa mulẹ, ati pe ki lo fa a to fi jẹ pe oun ni Kọmureedi Ajasa yan fun ẹgbẹ TAMPAN.

Iyalẹnu lo jẹ pe ohun ti Ọba Pedepede sọ ni pe lootọ ni Gomina Ajasa yan oun gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ lori ọrọ iroyin, ṣugbọn toun ko le sọ pato idi ẹ, ayafi ti ẹni to yan oun ba sọ idi pataki to fi ri bẹẹ.

Lesekese ni AWIKONKO ti pe Gomina Ajasa lori foonu, ohun to si sọ ni pe “Bẹẹni, otitọ pọnbele, ko si irọ nibẹ. Ẹ jẹ ki n mu ọrọ mi bayii pe ẹni to ba ṣe daadaa, a fi ka sọ pe o ṣe daadaa, ka si gbe oriyin fun un. Ayọbami Adelani Akanji, ti wọn n pe ni Ọba Pedepede jẹ amugbalẹgbẹ lori ọrọ iroyin ninu ninu ẹgbẹ oṣere TAMPAN nipinlẹ Ogun, ki i ṣe fun emi nikan.

“Idi pataki ti mo fi yan an ni pe ki n to wọle gẹgẹ bi Gomina ẹgbẹ oṣere TAMPAN nipinlẹ Ogun ni Adelani ti n gbaruku ti mi, to si duro ti mi, gbogbo nnkan ti mo ba fẹ lati ọdọ ẹ lo n ṣe fun mi. Lẹyin ti mo wọle tan, ti mo tun yan igbimọ ti yoo ṣagbatẹru ifinijoye tawọn agbaagba ẹgbẹ wa wa a ṣe, ọpọ awọn Pedepede lo wa nibẹ lọjọ naa, bi ninu awọn ti mo yan yi ṣe jẹ ọmọ ẹgbẹ wa naa ni wọn tun jẹ ọmọ ẹgbẹ sọrọsọrọ, Adelani nikan ni mo ri i pe o ṣiṣẹ takuntakun.

“Ki i ṣe pe o dee de n ṣe e, o tun n lo owo apo ara ẹ lati fi ṣiṣẹ yi. O fi ara ṣiṣẹ,  o tun fi owo ba mi ṣe. Ẹni to ba si ṣe daadaa, dandan ni ka jẹ kawọn eeyan mọ pe o ṣe daadaa, idi ni yii to fi jẹ pe nigba ti mo daruko ẹ fun wọn, lẹsẹkẹsẹ ni wọn fi ontẹ luu pe oun ni ka lo.”

Nigba to n sọrọ lori awọn nnkan ti wọn tun n reti lọdọ Ọgbẹni Adelani, Ọba Pedepede bi wọn ṣe yan an yi, Gomina naa sọ pe “Mo ni igbagbọ ninu lori awọn nnkan to ti ṣe ki n to o de bẹ ati lẹyin ti mo de bẹ pe yoo ṣe ju bẹẹ lọ nitori pe gbogbo ọna patapata ni mo ti gba ṣe idanwo fun un, to si yege.

“Ẹni to ba fẹẹ ṣe oju aye, ko ni i mọ pe eeyan n ṣọ oun, ẹni to ba si fẹẹ ṣe nnkan daradara, ko tun ni mọ pe eeyan n ṣọ oun, aimọye idanwo lo ti la kọja, to si yege. O dami loju pe eeyan to n duro ti i ẹnikeji lasiko to ba le ni Ọgbẹni Adelani.

Nigba to n gbawọn eeyan lamọnran, paapaa awọn to wa nilana Ọba Pedepede yan laayo yi, Ọkunrin naa sọ pe “Mo sọ fun un yi lakọkọ pe awọn ti wọn jọ jẹ Pedepede bi i marun  ni a ti ko mọra ta a si ri bi onikaluku wọn ṣe ṣe ko too di pe a yan Ọgbẹni Adelani.

“Nnkan tonikaluku ba ṣe silẹ lo maa pada de ba, ni mo ṣe ma a gba wọn lamọnran pe bi wọn ba pe wa fun nnkankan, ka gbiyanju lati ko ipa ti wa. Ninu ko si aaye, leeyan gbọdọ wa aaye lati ṣe iwọnba to le ṣe kawọn eeyan le jẹri si i.

“Emi funra mi ti mo pada di Gomina lonii, mo le sọ ọ niwọnba pe ọpọ awọn nnkan ti mo ti ṣe sẹyin lo mu kawọn eeyan mi, paapaa awọn ti wọn tun jẹ ọga fun gbaruku ti mi. Ki i ṣe emi nikan ni mo gbe igba apoti Gomina, mo lawọn to ju mi lọ, mo lawọn to ti bi iru mi lọmọ ti wọn gba fọọmu, ṣugbọn to jẹ pe emi ni wọn mu.”

Adura wa ni pe Ọlọrun yoo fun Ọba Pedepede ni oore-ọfẹ ati agbara lati oke wa lati le lo ipo naa daadaa. Amin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI