WAHALA DE: ỌLỌTA KỌJU IJA SI ALAKE ILẸ ẸGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 23, 2019

WAHALA DE: ỌLỌTA KỌJU IJA SI ALAKE ILẸ ẸGBA

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, nnkan ko fi bẹẹ rọgbọ laarin Ọlọta tiluu Ọta, Ọba (Ọjọgbọ) Adeyẹmi Ọbalanlegẹ ati Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ latari bi wọn ṣe sọ pe Alake n gbiyanju lati yan Baalẹ sagbegbe kan niluu Awori, eyi ti wọn ni ko tẹ awọn kan lọrun.

Bo tilẹ jẹ pe o ti pẹ ti awuyewuye naa ti n lọ labẹlẹ, ṣugbọn lọjọ Mọnde ana ni ọrọ naa tun pada jẹ jade sita gbangba, ti Ọlọta tiluu Ọta, Ọba Ọbalanlẹgẹ si n rawọ ẹbẹ pe kijọba ipinlẹ Ogun atawọn tọrọ kan tete pe Alake ṣeyin, nitori pe o n kọja aaye ẹ, toun ko si ni i gba fun un.

Ohun ta a gbọ ni pe, lọjọ Mọnde ana ni Ọba Ọbalanlẹgẹ ṣabẹwo lọ si ilu Mẹsan-Ọta nibi to ti jade wa, paapaa lọdọ Baalẹ Muiz Ọdunoye to ṣaaju awọn ara agbegbe naa gba a lalejo nileewe alakọbẹrẹ Mẹsan.

Nibi ipade naa la gbọ pe Baalẹ Muiz ti fẹsun kan Alake tilẹ Ẹgba pe o n gbiyanju lati da wahala silẹ niluu naa, lori bo ṣe n gbiyanju yan ayederu Baalẹ min in si Mẹsan-Ọta, to si lawọn ko gba fun un.

Oloye Muiz wa a rọ Ọba Ọbalanlẹgẹ pe ko lo ipo ẹ lati da si ọrọ naa, ko si bawọn gbe igbesẹ to tọ lati ri i pe igbesẹ ti Alake n gbe naa ko wa simuṣẹ, paapaa bo ṣe jẹ ilu Awori ko si labẹ Alake, bi ko ṣe Ọlọta.

Bakan naa nigba toun naa n sọrọ, ọkan lara awọn agbaagba lagbegbe naa, Alagba Alani Adetunji bẹ awọn alalẹ pe ki wọn dide ja fun wọn, ki wọn fa ibi yọ sawọn to ba n gbiyanju lati da wahala silẹ lọdọ wọn.


Ọba Ọbalanlẹgẹ ninu ọrọ ti ẹ dupẹ gidigidi lọwọ awọn araalu fun bi wọn ṣe duro ti ilẹ Baba wọn ti wọn ko si jẹ kawọn kan wa ja a gba lọwọ wọn.

O wa ṣeleri fun wọn pe ko si apa kan, tabi agbegbe kan nilẹ Awori toun yoo laju silẹ fawọn kan lati gba mọ wọn lọwọ lasiko toun fi jẹ Ọba alaye.


Bẹẹ lo rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Ogun Gomina Amosun pe ki wọn tete kilọ fun Alake tilẹ Ẹgba pẹlu igbesẹ to n gbe naa.

Ninu ọrọ rẹ, o ni Agbara ati okun ti Ọlọrun fun un lo yẹ ko gbajumọ, ko si lo o fun idagbasoke ati ilọsiwaju awọn eeyan ẹ ni Ake, nijọba ibilẹ Abẹokuta South, ko si dẹkun lati ma a da si ọrọ oye jijẹ lagbegbe temi ni Ọta ati ilẹ Awori nibi."

Lara awọn ta a gbọ pe wọn tẹle Ọlọta lọjọ naa ni:
Akọgun Oruba Ọta, Ọba Wadudu Dẹinde; Ajana iluu Ijana Ọta, Ọba Clement Akinyẹmi; Balogun ilu Ọta, Oloye Idowu Balogu; Seriki ilu Ọta, Oloye Ọlanrenwaju Baṣọrun; Ẹkẹrin ilu Ọta, Oloye Bamigboye Ọṣunlabu; Aro ilu Ọta, Oloye Ezekiel Fadipẹ; Lisa ilu Ota, Oloye Dayọ Akindele Eleku; Ọtunba ilu Ọta, Ọtunba Ṣẹgun Johnson aatawọn min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI