WAHALA NLA RE O: MAPOLY DA IṢẸ SILẸ NITORI GOMINA AMOSUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 27, 2019

WAHALA NLA RE O: MAPOLY DA IṢẸ SILẸ NITORI GOMINA AMOSUN


Ṣe lọrọ fẹẹ le di boolọ o yago lọna laarọ ọjọ Fraide ana nigba tawọn oṣiṣẹ labẹ ẹgbẹ Senior Staff Association of Nigeria polytechnics (SSANIP) ati Non-Academic Staff Union of Education and Associated Institution (NASU), ẹka ti Moshood Abiọla Polytechnic so pe awọn ko ṣiṣẹ mọ, ayafi bijọba ba da si ọrọ to n lọ.

Ohun ta a gbọ ni pe latari owo oṣu mẹrin ti wọn ni Gomina Amosun jẹ wọn atawọn ẹtọ to tọ si wọn si wọn sọ pe Gomina ko fun wọn ni wọn loo fa a ti wọn fi fẹhonu wọn han sita lonii.

Bo tilẹ jẹ pe ọrọ naa ti n ja nilẹ tipẹ, to mu ki gbogbo oṣiṣẹ patapata nileewe naa da iṣẹ silẹ lọdun to kọja fun bi oṣu mẹfa gbako ki wọn to o pada laipẹ yi.

A gbọ pe oriṣiriṣi ipade lawọn oloye lawọn ẹgbẹ wọn yi ti ṣepade pọ pẹlu ijọba ipinlẹ Ogun, ṣugbọn ti wọn ni ko si ayipada rere kankan nibẹ.

Ṣaaju asiko yi, laipẹ yi, a gbọ pe awọn eeyan naa ti ṣepade, ti wọn si fun Gomina ipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun ni gbedeke ọsẹ kan lati fi san owo oṣu mẹrin to jẹ wọn, iyẹn owo oṣu kejila ọdun 2017, owo oṣu keji titi de oṣu kẹrin ọdun yi , ati pe lai jẹ bẹẹ, awọn yoo lọ si isinmi ọlọjọ pipẹ.

Nigba to n b’AWIKONKO sọrọ, Kọmureedi M.K Ọlawunmi to jẹ alaga  ẹgbẹ SSANIP, ẹka ti Mapoly sọ pe “Nnkan ta n beere fun ko pọ rara, ko da a, awa ko tako bi wọn ṣe da Poli tiluu Ipokia silẹ, bẹẹ lao tako bijọba ṣe yi orukọ MAPOLY pada si MAUSTECH, ohun ta n sọ pe ni pe kijọba fun wa lowo oṣu mẹrin to jẹ wa.

Bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yi, a ko ti i gba owo oṣu kejila ọdun 2017, oṣu keji si oṣu kẹrin ọdun 2019 ta a wa yi, bi o ba ni i parọ fun un yi, ọjọ Wẹside la padanu ọkan lara wa, to si jẹ pe lọsẹ meji sẹyin lati kọkọ padanu ẹni kan, to si jẹ pe eeyan mẹrin lati padanu laarin ọdun, idi ni pe wọn ko ri owo ọsibitu san.

"A ti bẹrẹ igbesẹ lati da iṣẹ ọlọjọ-gbọgbọrọ silẹ, ayafi bi gomina ba san gbogbo gbese to jẹ wa kato pada sẹnu iṣẹ pada."

Lara awọn to tun b'AWIKONKO sọrọ ti wọn kọ lati darukọ ara wọn ni wọn sọ pe "Ki Amosun fipo silẹ bayii, iya to fi n jẹ wa ti pọ ju, a ko ri owo ile san, awọn ọmọ ti ẹ si n lọ siluu Oyinbo lasiko to ba wun wọn , iya yi to gẹ."

Nigba to n sọ tẹnu ẹ, ọga agba ileewe giga gbogboniṣe naa, Dọkitọ Samson Ọdẹdina sọ pe suuru lọrọ naa gba, nitori pe awọn ti bẹrẹ ipade pẹlu ijọba ipinlẹ Ogun lati yanju ọrọ, toun si nigbagbọ pe awọn eeyan naa yoo pada sẹnu iṣẹ laipẹ.

Ṣugbọn sibe, ohun t'awọn kan n sọ ni pe wahala nla lo dele yi, nitori ti Gomina Amosun ko ṣetan lati dawọn lohun, t'awọn oṣiṣẹ yi naa si ti yari pe awọn ko ni i pada sẹni iṣẹ ayafi b'awọn ba gba ẹtọ wọn

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI