WỌN DA ẸJỌ IKU FAWỌN ỌMỌ NAIJIRIA MẸJỌ NI DUBAI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 19, 2019

WỌN DA ẸJỌ IKU FAWỌN ỌMỌ NAIJIRIA MẸJỌ NI DUBAI

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi lọwọ, ireti ọjọ ti wọn yoo yẹji iku fun wọn ni wọn reti bayii pẹlu bi ile ẹjọ ṣe ti paṣẹ pe ki wọn lọọ yeji fun awọn gendekunrin mẹjọ kan ti wọn ni iṣẹ adigunjale ni wọn fi n jẹun lorileede United Arab Emirates.

Awọn naa ni Chimuanya Emmanuel Ozoh, Benjamin Nwachukwu Ajah, Kingsley Ikenna Ngoka, Tochukwu Leonard Alisi, Chile Micah Ndunagu, atawọn mẹta min in ta a ko tii mọrukọ wọn dasiko ta a kọ iroyin yi tan.

AWIKONKO gbọ pe banki ati ibi tawọn eeyan ti n gba owọ lawọn ọdaran naa lọ ọ ja, ti wọn si kọ obitibiti owo lọ nibẹ, ṣugbọn ti ọwọ palaba wọn pada segi, iyẹn loṣu kejila ọdun 2016.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI