Aarẹ tẹlẹri lorileede
Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti sọ pe iku Ọba Fọlagbade
Ọlatẹru Ọlagbegi, tii ṣe
Ọlọwọ tiluu Ọwọ nipinlẹ Ọṣun to waja lọjọ Tuside to kọja yi ṣi n dabi ala loju
oun nitori pe ẹni ti ipa to ti ko lawujọ ko ṣe e gbagbe.
Oloye Ọbasanjọ lo sọrọ naa lonii lati ẹnu oludamọnran ẹ
lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni kẹhinde Akinyẹmi.
Ọbasanjọ ni kii ṣe iru asiko bayii lo yẹ ki Ọba Ọlagbegi
waja nitori pe asiko ti orileede Naijiria nilo rẹ julọ re e fun amọnran ati
iriri nla rẹ to kun fun ọpọlọpọ ọgbọ to le mu idagbasoke alaragbayida de ba
orileede yi.
Nitori naa, o ki gbogbo awọn Oloye atawọn olugbe ilu Ọwọ
patapata ku arafẹraku, ati pe ki wọn ṣe ara giri, bẹẹ lo ni oyẹ ki gbogbo awọn
ọmọ Naijiria maa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun iru eeyan ti Oloogbe naa jẹ ko to o
papoda.
Aarẹ tẹlẹri naa wa a ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi aṣiwaju
aṣa ninu awọn ọba alaye nile Yoruba, paapaa lorileede Naijiria.
No comments:
Post a Comment