AṢIRI TU, WỌN NI RONALDO RA MỌTO TO HAN JULỌ LAGBAYE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 1, 2019

AṢIRI TU, WỌN NI RONALDO RA MỌTO TO HAN JULỌ LAGBAYE

K si ọrọ meji tawọn eeyan kaakiri agbaye n jẹ lẹnu lasiko yi, bi ko ṣe ti mọto bọgini ti gbajugbaja agbabọọlu ẹgbẹ Juventus nn, Cristiano Ronaldo ṣẹṣẹ ra laipẹ yi, to si jẹ pe mọto naa lo han julọ lagbaye lasiko ta a wa yi.

Miliọnu mẹwaa Euro, iyen £10million ni wọn pe Bugatti ti Ronaldo ṣẹṣẹ ra naa, to si ti fi ya fọto, to tun gbe e sori ẹka ayelujara.

Ronaldo, ọmọ orileede Pọrtugal to kuro ninu ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid lọdun to kọja, to si ṣẹṣẹ gba ife ẹyẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Juventus.

Bugatti naa la gbọ pe wọn ṣẹṣẹ ṣe jade laipẹ yi, ati pe Ronaldo lẹni akọkọ ti yoo ra a, ti ko si tii sẹni to tii kowo le mọto naa, pẹlu bi wọn ṣe loo han to.

Ayẹyẹ aadọfa ọdun ni wọn ni ileeṣẹ to ṣe mọto Bugatti ‘La Voiture Noire’ naa fi ṣe nibi eto ti wọn pe ni Geneva Motor Show. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI