BI O ṢE LE YA FỌTO ALALOPẸ, ILEEṢẸ ARA ỌTỌ KAN RE E - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 18, 2019

BI O ṢE LE YA FỌTO ALALOPẸ, ILEEṢẸ ARA ỌTỌ KAN RE E

Ọpọ awọn eeyan ti wọn banujẹ lori bawọn fọto wọn ṣe n bajẹ, ti ko si latunṣe fun lilo, tabi akọsilẹ ọjọ iwaju. Ki i ṣe ahesọ tabi asọdun pe pupọ ninu awọn agbaagba atawọn ọdọ lasiko yi ni wọn ko ni fọto kekere wọn rara, eyi ti yoo jẹ ẹri lati maa fi dunnu igba kekere wọn.

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, oriṣiriṣi awọn oṣiṣẹ fọto yiya lo wọpọ lasiko yi, paapaa ti wọn n kaakiri ode ayẹyẹ lati ya fọto fawọn eeyan, to si jẹ pe fọto naa ki i pẹ ki wọn to o bẹrẹ sii bajẹ, pẹlu owo iyebiye ti wọn fi n ya awọn fọto.

Fọto jẹ ohun pataki to n jẹ ka mọ awọn iṣẹlẹ manigbagbe ọjọ to ti pẹ ati asiko yi, eyi tawọn Oyinbo si n jẹ ki imọ ijinlẹ ma a ba ọna bi a ṣe le maa ri fọto wa lo fun ọjọ pipẹ.
Bi wọn ba n ka awọn ileeṣẹ to mọ nipa bi wọn ṣe n fi fọto dara, paapaa nibi ayẹyẹ ọlọkan-o-jọkan kaakiri, odu ni ileeṣẹ TWELVE02, kii ṣaimọ foloko.

Ileeṣẹ TWELVE02 mọ nipa bi wọn ṣe n fi fọto dara, abi fọnran (video) lẹyin fẹẹ ya ni, bo si jẹ pe fọto ti wọn n ṣe sinu igi (Frame) lẹyin fẹẹ ṣe, awọn fọto agbekọ keekeeke ati nla ni wọn mọ nipa, wọn yoo tun ba a yin tun un ṣe lọna ti yoo tẹ ẹ yin lọrun.

Nọmba 50, Agọ-Egun, nitosi Iṣabọ ni ọfiisi wọn wa niluu Abẹokuta, to si jẹ pe kaakiri orileede Naijiria lawọn ti wọn mọ pataki iṣẹ wọn ti n pe wọn fun oriṣiriṣi ayẹyẹ ti wọn ba fẹẹ ṣe, ko da, awọn agbaagba nidi oṣelu lati lawujọ ọba alade ni wọn ko le fi awọn iṣẹ ileeṣẹ TWELVE02 ṣere rara.

Wọn mu nnkan rọrun debi pe bi ẹ ba pe wọn lori foonu, lẹsẹkẹsẹ ni yoo wa ba a yin nibikibiti ti ẹ ba wa fun oniruuru fọto ti ẹ ba fẹẹ ya, iyẹn bi ẹ ba ti dunadura tan, ẹ si tun le kan si wọn ni ọfiisi wọn.

Fun alaye lẹkunrẹrẹ, e pe awọn nọmba yi, lẹsẹkẹsẹ ni won yoo da a yin lohun, ko da, ẹ tun le fi atejiṣe ori ẹka ayelujara ibaraẹni-sọrọ, ti WhatsApp ranṣẹ si wọn:
08069472027, 08128780206.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI