Lọjọ Fraide ana lọwọ awọn ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọku-mọku, iyẹn EFCC niluu Abuja tun tẹ awọn ọmọ Yahoo mẹwaa min in, ti wọn si ni ọna bi wọn ṣe n jẹ aye fa-mi-lete-ki-n-tutọ lo koba wọn.
Awọn mẹwaa naa ni Habib Adeyẹmi, Lawal
Kẹhinde, Victory Jẹmibọr, Sọlomọn Enuneke, Ubgehi Joṣhua, Tosan Ogbe, Onajite Ejovwo, Anthony Igbonoeme, Tunde Azeez ati Adeyẹmi Habib.
A gbọ pe awọn ara agbegbe tọwọ ti tẹ wọn lo ta awọn ajọ EFCC lolobo, tawọn yẹn si bẹrẹ iṣẹ iwadii, ko to o di pe omi dilẹ lẹyin asunṣujẹ wọn.
Ajọ EFCC nigba ti wọn n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe awọn eeyan naa ko ni pẹ ẹ foju bale ẹjọ.
No comments:
Post a Comment