Ẹ GBA WA LỌWỌ WAHALA AWỌN FULANI N'IMẸKỌ AFỌN - ỌNỌREBU ỌLAIFA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 2, 2019

Ẹ GBA WA LỌWỌ WAHALA AWỌN FULANI N'IMẸKỌ AFỌN - ỌNỌREBU ỌLAIFA

Ko sẹni to wo bawọn Fulani daran-daran ṣe n fi gbogbo igba da wahala silẹ lorileede, paapaa nijọba ibilẹ Ẹgbado North, ti wọn si n dẹmi awọn eeyan legbodo, ti ko nii sunkun ikunlẹ abiyamọ.

Laipẹ yi l'AWIKONKO gbọ pe awọn Fulani tun kọja ija sawọn agbẹ lagbegbe Afọnmade, Iwoye ati agbegbe ẹ nibi tọpọ ẹmi ti ṣofo danu, tawọn min in si farapa yanna-yanna.

Ni bayii, ọkan lara awọn aṣoju-ṣofin agba siluu Abuja ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Ọnọrebu Ọlaifa Jimọh Arẹmu ti rawọ ẹbẹ sijọba apapọ, paapaa awọn agbofinro pe ki wọn tete wa a gba ẹmi awọn araalu la.

Ọnọrebu Ọlaifa ninu atẹjade to fi ṣowọ s'AWIKONKO lonii lo ti jẹ ko di mimọ pe bijọba ba tete gbe igbesẹ lati koju wahala naa, ki wọn si dẹkun, eyi yoo mu igbe aye irọrun de bawọn araalu, ti wọn yoo si finu fẹdọ lori orooro wọn sun.

Yatọ si yi, Ọnọrebu Ọlaifa tọpọ awọn eeyan tun n pe ni ỌJA gbawọn araalu lamọnran pe ki wọn yee fi ofin sọwọ ara wọn, ati pe ki wọn dẹkun lati maa ṣe idajọ lọwọ ara wọn, dipo bẹẹ, ki wọn ta awọn ọlọpaa lolobo.

Bakan naa lo tun sọ pe kawọn ileeṣẹ eleto aabo kaakiri tete dide iranlọwọ fawọn eeyan agbegbe Imẹkọ Afọn, nitori pe ẹmi awọn eeyan ṣe pataki.

Bẹẹ lo ṣeleri fawọn araalu pe lara awọn nnkan toun yoo gbajumọ ni eto aabo, paapaa lati ri i pe wahala awọn Fulani naa dinku ni gbogbo awọn agbegbe toun n ṣoju wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI