VALENCIA GBE BẸẸDI IYA LỌ SILE ARSENAL, NI CHELSEA BA GBA ỌỌMI AYO PẸLU FRANKFURT - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 2, 2019

VALENCIA GBE BẸẸDI IYA LỌ SILE ARSENAL, NI CHELSEA BA GBA ỌỌMI AYO PẸLU FRANKFURT

Pẹlu omijẹ ni ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Valencia fi kuro ni Ẹmirate lalẹ oni nigba ti ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal fibinu doju ti wọn pẹlu aami ayo mẹta si ẹyọkan.

Ohun tawọn to wo idije naa n sọ ni pe ẹgbẹ agbabọọlu Valẹncia ni wọn fọwọ kekere gba nla, nigba ti Mouctar Diakhaby gba goolu wọle niṣẹju mọkanla ti idije naa bẹrẹ.

Ibinu ni Arsenal fi bẹrẹ sii da awọn goolu naa pada niṣẹju mejidinlogun, nigba ti Alexandre Lacazette gba bọọlu wọle, to si tun gba min in wọle niṣẹju mẹrindinlọgbọn, ki wọn to o fi ọba le e nigba to ku diẹ ki idije naa pari. Pierre Emerick lo pari idije naa pẹlu goolu kẹta.

Iroyin min in to fara pẹ ẹ ni ti ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti wọn fagidi da goolu kan ti ẹgbẹ agbabọọlu Frankfurt gba wọle pada fun wọn.

pabo ni gbogbo igbiyanju Chelsea pada ja si, to si mu ki wọn pari idije naa pẹlu aami ayo kan si ookan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI