EEMỌ RE O: OKU ỌMỌ TUNTUN POORA L'ỌSIBITU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 20, 2019

EEMỌ RE O: OKU ỌMỌ TUNTUN POORA L'ỌSIBITU

Ariwo eemọ ree, ẹ maa woo niran ni ọpọ awọn ero to de gbagede ileewosan nla Ondo state specialist Hospital nilu Akurẹ ni ọjọ Abamẹta to kọja yi nibi ti okiki ti kan pe oku ọmọde jojolo kan ti wọn gbe si inu ile igbokupamọsi, ileewosan naa ti poora.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ọjọru ni wọn gbe oku arabinrin kan ati ọmọde jojolo to ṣẹṣẹ bii ni abiku wa si ileewosan nla naa lẹyin ti wọn ku nigba ti obinrin naa n rọbi ni ileewosan awọn ọlọpaa to wa ni ilu Akurẹ kan naa.

Amọṣa ọrọ di womi-n-wo ọ nigba ti awọn ẹbi Arabinrin naa de ile igbokupamọsi ileewosan nla Ondo state specialist Hospital nilu Akurẹ ni ọjọ Abamẹta lati gbe oku oun ati ẹjẹ ọrun ti wọn jọ jalaisi naa.

Si iyalẹnu wọn ati ọpọ eeyan nibẹ lati rii pe oku Arabinrin naa nikan ni wọn ba, wọn ko ri oku ọmọ tuntun jojolo naa gbe.

Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe oku Arabinrin yii ati ibi ọmọ tuntun to bi ni nikan ni wọn ba, ẹnikan ko si lee sọ ohun to gbe oku ọmọ tuntun naa kuro nile igbokupamọsi naa.

Bakan naa ni 'awọn oṣiṣẹ ile igboku pamọsi naa ko lee sọ bi oku ọmọ tuntun naa ṣe poora.'

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ to si ni awọn ọlọpaa yoo gbe awọn oṣiṣẹ ileewosan naa ti ọrọ ọhun kan fun ifọrọwanilẹnuwo laipẹ.

Amọṣa, Fẹmi Joseph ni titi di igba ti a fi n ko iroyin yii jọ, "wọn ko tii fi panpẹ ofin mu ẹnikẹni lori ọrọ naa.

Bakan naa, Dokita Wahab Adegbenro to jẹ Kọmiṣọna feto ilera ni ipinlẹ Ondo ṣalaye pe wọn ti fa ọrọ naa le awọn ọlọpaa lọwọ.

O ni ohun ti ijọba n duro de bayii ni 'abajade iwadii awọn ọlọpaa' lori ọrọ naa.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI