AYAJỌ AWỌN ỌMỌDE, WỌN FẸẸ DA GBAJABIAMILA LỌLA L’EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 21, 2019

AYAJỌ AWỌN ỌMỌDE, WỌN FẸẸ DA GBAJABIAMILA LỌLA L’EKOO

Ọjọ Mọnde ọsẹ to m bọ ni wọn fẹẹ fi oye tuntun da olori ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin to pọ ju niluu Abuja, Ọnọrebu Fẹmi Gbajabiamila lọla, ta a si gbọ pe gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun eto ayẹyẹ ayajọ awọn ọmọde naa ti wọn pe ni Alaka Children's Day.

Idalọla naa ni wọn pe ni Face of Alaka Children's Day tọdun 2019 latari awọn ipa to ti ko laarin awọn eeyan ẹ, lawọn asiko to fi wa nipo. Ọjọ kẹtadinlọgbọn 

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Alaka Community Recreation Centre to wa ni Surulere ni eto ayẹyẹ naa ti fẹẹ waye, tawọn eeyan jankan-jankan yoo si peju sibẹ.

Awọn alakoso MediaGate atawọn Alaka ara LSDPC Community Development Association la gbọ pe wọn panupọ lati bu ọla fun Ọnọrebu Gbajabiamila naa, ti wọn si tun fẹẹ fi ṣe ambasidọ wọn fọdun 2019.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI