EYI LAWỌN ILERI TI DAPỌ ABIỌDUN TUN ṢE FAWỌN OṢIṢẸ LỌJỌ AYAJỌ WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 2, 2019

EYI LAWỌN ILERI TI DAPỌ ABIỌDUN TUN ṢE FAWỌN OṢIṢẸ LỌJỌ AYAJỌ WỌN

Gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ogun, ti wọn yoo si ṣe ibura fun lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii, Ọmọba Dapọ Abiọdun, tun ti mu da awọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa loju pe gbogbo ileri toun ṣe pẹlu wọn lakooko ipolongo oun loun yoo mu ṣẹ fun wọn, boun ba depo.

O sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Wẹside ana, eyi to fi ki awọn oṣiṣẹ ku ayajọ wọn ti wọn ṣe loni in, nibẹ lo ti ṣajọyọ pẹlu wọn.

Atẹjade naa lo ka bayi pe “Mo bawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣajọyọ ayajọ ti wọn n ṣe loni-in, inu mi dun pe ayẹyẹ ti wọn ṣe lọdun yii jẹ nnkan ayọ ati ipadabọ sijọba ti yoo bẹrẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu yii”.

“Ki ẹ Ie mọ pe mi o gbagbe, mo fẹẹ muu wa si iranti yin lara awọn ileri ti mo ṣe lakooko ipolongo lati le mu igbe aye dẹrun fawọn oṣiṣẹ, ki ẹ le mọ pe mo fi yin sọkan.

Idasilẹ ileeṣẹ ti yoo maa ri bawọn oṣiṣẹ yoo ṣe maa ṣe daadaa ati imu-ayedẹrun fun wọn.

Gbigba awọn olukọ siṣẹ lọna ti yoo dọgba pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba.

Ṣiṣe atunṣe lori awọn oṣiṣẹ fẹyinti ati idasilẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fẹyinti tipinlẹ ati lawọn ijọba ibilẹ atawọn nnkan mii in ta jọ so papọ.

Bakan naa lo tun fikun ọrọ ẹ pe gbogbo ọna lawọn yoo tun gba lati rii pe awọn ṣamulo ofin to gbe igbimọ laarin awọn oṣiṣẹ ati aṣoju awọn oṣiṣẹ lati ṣiṣẹ lori awọn owo ajẹmọnu ti wọn jẹ awọn oṣiṣẹ.

O ni ọsẹ akọkọ ti wọn ba gbakoso ni wọn yoo ṣagbekalẹ igbimọ naa.

Dapọ Abiọdun tun sọ pe awọn yoo rii pe awọn oṣiṣẹ nu awọn aṣoju rere ninu ijọba oun eyi ti yoo jẹ ki irẹpọ tun wa laarin wọn.

O wa rọ awọn oṣiṣẹ ki wọn lo akoko yii lati ṣatilẹyin fawọn tijọba tuntun ba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI