IDI TAWỌN ONIROYIN KO FI TII RI NNKAN BURUKU KỌ NIPA MI - TEMITAYỌ ṢAKIRA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 2, 2019

IDI TAWỌN ONIROYIN KO FI TII RI NNKAN BURUKU KỌ NIPA MI - TEMITAYỌ ṢAKIRA

Kii ṣe tẹnu, ki ẹ to o wo sinima marun lasiko yi, bi ẹ ko ba ri Temitayọ Adeniyi, ọmọ bibi ilu Ikẹrẹ Ekiti ninu mẹta, dandan ni ki ẹ ba a pade ninu meji, nitori pe ọkan pataki lara awọn irawọ oṣere ti wọn n lo ju lasiko yi ni.

Lai pẹ yi ni ọmọbinrin tọjọ ori ẹ ko tii ju ọdun marundinlọgbọn lọ naa tu aṣiri idi tawọn oniroyin ko ti i fi ri nnkan buruku kọ nipa ẹ, to si ni igbe aye toun n gbe yatọ si tawọn toku.

Temitayọ tawọn ololufẹ ẹ tun mọ si Ṣakira nigba to n ba ọkan lara awọn gbajumọ oniroyin nileeṣẹ African Magic Yoruba, Arabinrin Adedoyin Kukọyi sọrọ lori eto Gbajumọ naa sọ pe oun kii ṣe ọmọ jade-jade bi i tawọn oṣerebinrin toku, ati oe jẹjẹ loun n lọ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Awọn oniroyin ko ti i gbe iroyin buruku sita nipa mi ri. Mi ọ le sọ pe nnkan bayii lo mu ki temi yatọ laarin awọn ẹlẹgbẹ mi, ati pe boya ki n sọ pe nitori igbe aye ti mo n gbe, ati pe mi o kii ṣe ọmọ jade-jade, oṣere tiata lasan ni mi.

"Ọpọ awọn oniroyin gan an ni ko pade mi ri. Ile ni mo maa n pada si ti n ba kuro lẹnu iṣẹ. Ko sibi ti mo n jade lọ, iṣẹ mi ni mo si doju kọ, yatọ sawọn nnkan ti mo tun n ṣe ti kan han sita. Boya nitori ẹ ni wọn ko ṣe ri nnkan buruku kọ nipa mi."

Nigba to n sọrọ lori ọkunrin to fẹran lati fi ṣe ade ori, o ni "Lakọkọ naa, irisi ẹ niwaju mi lo maa mu mi pinu boya ki n gba fun, tabi ki n ma gba fun. Irisi yẹn gan an lo ṣe koko.

"Ka so pọ naa tun ṣe koko, bi ọkunrin ba ga, to si rẹwa debi to ṣe e ri mọ eeyan, bi a ko ba pade ara wa, ka si maa sọrọ, mi o le mọ nnkankan nipa ẹ. To ba si jẹ ọkunrin ti ko ba ga, ti ko si rẹwa, ta a ba pade, a le ṣiṣẹ debi ti ọrọ wa ti maa ye ara wa."

Ohun tawọn to gbọ ọrọ ti ọmọbinrin ti ko tii l'ọkọ yi n sọ ni pe ko ni suuru, asiko naa yoo to o de, toun naa yoo bẹrẹ si i ri ara rẹ kaakiri ayelujara, iyẹn bi ko ba fọwọ sibi tọwọ n gbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI