FỌTO: Ẹ WO BAWỌN FULANI ṢE DANA SUN AWỌN EEYAN MỌLE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 5, 2019

FỌTO: Ẹ WO BAWỌN FULANI ṢE DANA SUN AWỌN EEYAN MỌLE

Lọjọ Fraide to kọja yi lawọn Fulani daran-daran tun gbe iṣe wọn jade, ti wọn kọlu awọn ara abule Rekwechongu nijọba ibilẹ Bassa, ipinlẹ Palteau. Eeyan meji la gbọ pe wọn dana sun mọle lọjọ naa.

Ni nnkan bi aago mẹwaa alẹ ọjọ naa la gbọ pe awọn Fulani yi yawọ abulẹ naa, lasiko tawọn eeyan ti n sun.

Awọn meji ta a gbọ pe wọn dana sun mọle naa ni Adi Zere ti wọn lọmọdun mejilelọgọta(62) ni ati ọlọpaa kan ti wọn [lọmọdun marundinlogoji (45) loun jẹ.

Yatọ si eyi, a gbọ pe ṣọọṣi meji, ogunlọgọ ile, awọn ounjẹ loriṣiriṣi, ohun ọsin atawọn oko ti wọn da, ti wọn lowo wọn le ni miliọnu naira la gbọ pe awọn Fulani naa dana sun.









No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI