IṢẸ IHINRERE NI ABRAHAM, AGUNBANIRỌ BA JADE KURO NILE, LAWỌN BOKO HARAM BA JII GBE SALỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 5, 2019

IṢẸ IHINRERE NI ABRAHAM, AGUNBANIRỌ BA JADE KURO NILE, LAWỌN BOKO HARAM BA JII GBE SALỌ

Titi dasiko ti a ṣakojọpọ iroyin yi tan la ko ti i gbọ pe awọn Boko Haram ti wọn ji ọkan lara awọn agunbanirọ to n sin orileede Baba rẹ niluu Maiduguri ti i ṣe ipinlẹ Borno ni ko ti i fi silẹ.

Agunbanirọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Abraham Amuta la gbọ pe iṣẹ ihinrere lo ba lọ pẹlu pẹlu Pasitọ ṣọọṣi ijọ Living Faith ti Baba Oyedepo lọ, lọsẹ meji sẹyin, ti wọn si ni alọ ẹ ni wọn ri, wọn ko ti i ri apadabọ ẹ dasiko yi.

Wọn ni Abraham Amuta nikan lọmọ tawọn obi ẹ bi, ti wọn si n rawọ ẹbẹ sijọba apapọ pe ki wọn ran awọn lọwọ lati gba a kuro lọwọ awọn ẹṣin o kọ iku yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI