FRANCE 2019: EYI LAWỌN TI YOO LỌ ṢOJU SUPER FALCONS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 25, 2019

FRANCE 2019: EYI LAWỌN TI YOO LỌ ṢOJU SUPER FALCONS

Asisat Oshola, Desire Oparanozie ati Onome Ebi jẹ pataki lara ikọ ẹlẹnimẹtalelogun ti yoo ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu obinrin ti Naijiria, Super Falcons ni France.

Idije naa ni yoo jẹ ti aṣekagba idije ife agbaye awọn obinrin l'orilẹ-ede France.

Oludari eto ibanisọrọ nileeṣẹ ajọ to n mojuto ere idaraya ni Naijiria, NFF, Ademọla Ọlajire ninu ikede kan to fi sita l'alẹ ọjọ Ẹti sọ pe orilẹ-ede Austria nibi ti Super Falcons wa lọwọlọwọ fun igbaradi ni olórí akọnimọọgba wọn, Thomas Dennerby ti kede orukọ naa.
Awọn mi i ti orukọ wọn tun wa ninu ikọ naa ni Tochukwu Oluehi, Chiamaka Nnadozie, Alaba Jonathan, Osinachi Ohale, Faith Michael, Chidinma Okeke, Rita Chikwelu, Ngozi Okobi-Okeoghene, Halimatu Ayinde, Ogonna Chukwudi.

Bakan naa ni Evelyn Nwabuoku, Amarachi Okoronkwo, Uchenna Kanu, Fransisca Ordega, Uchenna Chinaza, Anam Imo, Rasheedat Ajibade ati Chiwendu Ihezuo yoo kopa.

Ọjọ Kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun 2019 ni Super Falcons yoo gbera kuro ni Austia lọ si orilẹ-ede France ti idije naa yoo ti waye.

Wọn yoo si koju Norway, Korea ati France ni ipele akọkọ.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI