GOMINA AJIMỌBI YAN OLORI AWỌN OṢIṢẸ TUNTUN L’ỌYỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 25, 2019

GOMINA AJIMỌBI YAN OLORI AWỌN OṢIṢẸ TUNTUN L’ỌYỌ

Bo ṣe ku ọjọ bii marun-un ki saa iṣakoso Gomina Abiọla Ajimọbi tiinlẹ yọ pari, Gomina naa ti bu ọwọ lu olori awọn oṣiṣẹ tuntun nipinlẹ naa, Arabinrin Ọlọlade Agboọla.

Ni kete ti olori awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa tẹlẹ, Arabinrin Hannah Ogunẹsan fẹyinti ni ijọba yan Arabinrin Agboọla pe ko gba ipo lọwọ ẹ, ki iṣẹ ma ba a duro nipinlẹ naa.

Ọjọ Fraide ana ni eto naa waye nile-iṣẹ ijọba to wa lagbegbe Agodi, Ibadan.

Ọmọ bibi ilu Ibadan ni Arabinrin Agboọla, oun ni iyawo Ọnọrebu Hosea Agboọla tawọn eeyan mọ si Hallelujah.

Bakan naa ni obinrin naa tun jẹ akọwe agba l’ẹka to n ri sọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya (Permanent Secretary, Ministry of Youth and Sports).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI