IDI TI MO ṢE FIJỌBA GOMINA AMOSUN SILẸ LOJIJI - KỌMIṢANA, BABAJIDE OJUKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 15, 2019

IDI TI MO ṢE FIJỌBA GOMINA AMOSUN SILẸ LOJIJI - KỌMIṢANA, BABAJIDE OJUKO

Laipẹ yi la gbe iroyin kan jade sita pe Kọmiṣana fọrọ Ijọba Ibilẹ ati Oye Jijẹ nipinlẹ Ogun, Oloye Babajide Ojuko ti kọwe fipo rẹ silẹ lojiji bi ijọba Gomina Amosun ṣe ti n kasẹ nilẹ lọjọ meloo kan si asiko ta a wa yi.

Ta a si ṣeleri pe a maa mu ẹkunrẹrẹ rẹ wa fun un yin, ni bayii, AWIKONKO ti ri lẹta ifiposilẹ naa gba, eyi to sọ pataki idi ti Baba naa ṣe kọwe fipo silẹ lọjọ Tuside ana.

Lẹta naa ka bayii pe "Lakọkọ naa, mo fẹẹ fi tọkan-tọkan dupẹ lọwọ yin fun anfaani ti ẹ fun mi lati sin ipinlẹ yi labẹ ijọba yin paapaa ni saa iṣakoso ẹlẹẹkeji yin gẹgẹ bi Gomina. Mo fẹẹ fi da a yin loju pe anfaani ti ko wọpọ lo jẹ fun mi, ati pe titi aye ni maa fi maa dupẹ.

"Sibẹ, o dun mi de isalẹ ọkan mi pe mo fun ọga ti mo fẹran ju niwe ifiposilẹ.

"Nipa iṣẹ ti a gbe lemi lọwọ, Mo ṣoju awọn eeyan mi nilẹ Awori, ijọba ibilẹ mi ati ipinlẹ Ogun lalapọ, ko si nnkan ti mo le ṣe ju pe ki n pada sile lọọ bawọn eeyan atawọn ẹbi mi pẹlu ibalẹ ọkan.

"Awọn iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ laipẹ jẹ ki n gbagbọ pe awọn ipinu yi le ma jẹ ki otitọ farahan bi mo ba tẹsiwaju lati maa di ipo yi mu gẹgẹ bi Kọmiṣana fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ. Ohun ti yoo tẹyin ẹ yọ ni pe maa di ajoji niwaju awọn eeyan.

"Pẹlu ọjọ ori mi, mi o le gba a.

"Ọga mi, gẹgẹ bi ibi ti mo ti n bọ bi oṣiṣẹ ijọba, ẹkọ ti mo ri gba ni pe ki n maa gbọnran, ki n si ni itẹriba si ọga mi, ṣugbọn pẹlu aṣẹ ti ẹ gbe kalẹ laipẹ yi lori ọrọ Ọba lawọn agbegbe kan niluu Ọta tako ẹri ọkan mi pupọ, ati ifẹ ọkan awọn eeyan mi ti mo n ṣoju.

"Lẹẹkan si, ẹ ṣi n jẹ ọga mi nidi oṣelu ati ẹgbọn mi. Mo dupẹ lọwọ yin fun ọwọ, ifẹ ati anfaani ti ẹ fun mi lati ṣiṣẹ sin awọn eeyan rere nipinlẹ Ogun."

Ọpọ awọn to gbọ nipa nnkan to ṣẹlẹ yi lọrọ naa ṣi n ya lẹnu titi dasiko yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI