GOMINA AMOSUN KO GBA KI N FI IṢẸ SILẸ O - KỌMIṢANNA, BABAJIDE OJUKO PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 17, 2019

GOMINA AMOSUN KO GBA KI N FI IṢẸ SILẸ O - KỌMIṢANNA, BABAJIDE OJUKO PARIWO SITA

...A ti yanju ọrọ wa - Ojuko
Kọmiṣanna f'ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ogun, Oloye Babajide Ojuko ti sọ pe Gomina Ibikunle Amosun ko gba iwe ifiposilẹ toun kọ ranṣẹ sii lọjọ Wẹside ijẹta wọle rara, toun si lawọn yoo jọ pari saa yi ni.

Bẹ o ba gbagbe, ana tii ṣe Tọside la gbe iroyin kan jade sita pe Kọmiṣanna f'ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ogun, Oloye Jide Ojuko kọwe fiṣẹ silẹ lojiji, to ṣalaye idi to fi ri bẹẹ.

Laarọ oni ni Oloye Jide Ojuko tun b'awọn oniroyin sọrọ pe ọrọ ko ri bo ṣe lọ mọ nitori pe ija ololufẹ meji ni nnkan to ṣẹlẹ naa, ati pe oun ko fẹẹ ṣẹ awọn eeyan oun.

Ninu ọrọ Oloye Ojuko lo ti sọ pe "Mo fẹ ki ẹ mọ nipa ayipada tuntun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ bayii nipa ikọwefiposilẹ mi.

"Mo fẹ ki ẹ mọ pe lẹta naa je lẹta laarin ololufẹ meji. Mo nifẹ Gomina mi, oun naa si nifẹ mi pẹlu.

"Gomina ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun loun ko gba lẹta ti mo kọ ranṣẹ lati fiṣẹ silẹ wọle, eyi t'awọn iwe iroyin kaakiri ti gbe.

"Nipa ayipada tuntun yi, mo ti pada sipo mi gẹgẹ bi Kọmiṣanna, ati pe mo fẹẹ jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn nnkan to rọ mọ ipinu mi lati fipo silẹ tẹlẹ nijọba ti gbe yẹwo.

"Ẹ jẹ ki n tun fi asiko yi jẹ ki gbogbo eeyan mọ pe lẹta ti mo kọ lati f'iṣẹ silẹ ni pupọ awọn iwe iroyin ko tunmọ daadaa, ti mọ si n fi asiko yi dupẹ lọwọ awọn ara agbegbe Ọta fun imọ ati oye ti wọn ni.

"Emi ṣi ni Kọmiṣanna f'ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ nipinlẹ Ogun digba tijọba yi yoo fi ko igba wọle."

Siwaju sii lo tun sọ pe idi pataki toun fi kọwe fipo silẹ tẹlẹ ko ni nnkan ṣe pẹlu t'awọn Ọba ti wọn ba ara wọn ja, tori pe Kọmiṣanna ipinlẹ Ogun loun, oun kii ṣe Kọmiṣanna Awori, ati pe oun n'igbagbọ pe iyanju yoo wa laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI