IDIBO ỌṢUN: ABURO ADELEKE NILE ẸJỌ TO GA JULỌ NI YOO DA ADELEKE LARE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 12, 2019

IDIBO ỌṢUN: ABURO ADELEKE NILE ẸJỌ TO GA JULỌ NI YOO DA ADELEKE LARE

Ti ina ko ba tan laṣọ, ẹjẹ kii tan leekana lọrọ igbẹjọ idibo gomina ipinlẹ Oṣun da fawọn oludije ẹgbẹ osẹlu PDP Ademola Adeleke, lẹyin ti aburo rẹ Dele sọ pe Adeleleke yoo bori nile-ẹjọ to gaju lọ.

Ẹ o ranti wi pe ile ẹjọ kotẹmilọrun l'Abuja da idajọ igbimọ igbẹjọ idibo gomina ipinlẹ Oṣun to waye lọdun 2018 to sọ pe Adeleke lo jawe olubori ninu ibo ọhun nu ti o si ni Gomina Gboyega Oyetola lo wọ le.

Ṣugbọn Dele ni o da oun loju t'ada pe ile ẹjọ to ga julọ naa yoo da idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun nu.

Adeleke kọkọ bori pẹlu ibo 254,698 ti Gomina Oyetola to jẹ oludije fẹgẹ APC si ni 254,345 ninu idibo to waye lọjọ kejilelogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2018.

Ṣugbọn Oyetola la Adeleke mọ lẹ lẹyin ti afikun idibo waye lawọn ibudo idibo kan ti wọn wọgile ibo.

Dele ṣalaye pe idajọ erefee ni ile ẹjọ kotẹmilọrun da, ati pe ile ẹjọ naa ko foju sunnunkun wo ẹjọ ọhun ki o to dajọ.

O fikun ọrọ rẹ pe gbogbo eeyan nipinlẹ Oṣun lo mọ pe Adeleke lo wọ le ibo gomina nipinlẹ Oṣun.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI