IJỌBA IPINLẸ KWARA DA ỌGA AGBA FASITI KWARA DURO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 9, 2019

IJỌBA IPINLẸ KWARA DA ỌGA AGBA FASITI KWARA DURO

'Ki lo le fa a, ki lo ṣẹlẹ to le to bẹẹ' nibeere tawọn ọmọ Naijiria kaakiri agbaye n beere lọwọ ara wọn pẹlu igbesẹ ijọba apapọ orileede yi lati da ọga agba fasiti Kwara, iyẹn Kwara State University, Ọjọgbọn Abdulrasheed Na’Allah duro lojiji.

Idi ni pe, ojiji niwe idaduro naa tẹ ọkunrin naa lọwọ, ti wọn ko si sọ idi pataki ti wọn fi da a duro lọjọ Mọnde, ijẹrin.

Loju ẹsẹ ti wọn ti paṣẹ pe ki Ọjọgbọn Kenneth Adeyẹmi gbakoso gẹgẹ bi ọga agba fidihẹ, bẹẹ ni wọn tun jawe lọọ gbele ẹ fungba diẹ fun Ọjọgbọ Na'Allah lai sọ igba ti yoo pada sẹnu iṣẹ.

Ibẹrẹ saa ọdun 2009 si 2010 ni wọn yan Ọjọgbọn Na'Allah, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta (56) gẹgẹ bi ọga agba fasiti naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI