Lonii ni Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Oṣun labẹ
asia ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo ọdun 2018, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti foju ba ile
ẹjọ Majisireti to wa ni Mpape l'Abuja.
Ileeṣẹ ọlọpaa fi ẹsun marun ọtọọtọ kan an. Si eyi, Sẹnetọ Adeleke ni ohun ko jẹbi awọn ẹsun naa ti adajọ Mohd Zubairu si gba beeli
rẹ pẹlu iye owo miliọnu meji naira ati pipese oniduro kan bakan naa. Alukoro
ile iṣẹ ọlọpaa, Frank Mba lo fi ọrọ yii lede pe wọn gbe sẹnetọ naa si atimọle
lori ẹsun to nii ṣe pẹlu lilo ayederu iwe ẹri.
Ẹwẹ, awọn oniroyin to fọrọ wa a lẹnu wo ni ko sọ
pato awọn ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ.
Lọjọ Aje, ẹgbẹ oṣelu PDP fẹsun kan pe wọn n pete
lati fun Adeleke ni majele ni.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ọ, ana ni PDP ní Ọlọ́pàá ti mú
Sẹ́nétọ̀ Ademọla Adeleke sí àhámọ́ latari ọrọ ti ẹgbẹ ṣapejuwe gẹgẹ bii
"aibọwọ fun alakalẹ ofin ile ẹjọ giga".
No comments:
Post a Comment