NITORI OUNJẸ, ILE ẸJỌ AMẸRIKA RAN IYA ARUGBO LẸWỌN ỌDUN MẸẸDOGUN PERE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 7, 2019

NITORI OUNJẸ, ILE ẸJỌ AMẸRIKA RAN IYA ARUGBO LẸWỌN ỌDUN MẸẸDOGUN PERE

Kani iya arugbo nni, Arábìnrin Olurẹmi Adelẹyẹ ti di èrò ẹwọ̀n ọdún mẹ́ẹ̀dógun nítori ó dá ọmọ oṣù mẹ́jọ kilẹ̀ láti rọ ọ́ ní ounjẹ ni Maryland ilẹ Amẹríkà.

Adeleye ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rin bú sẹkún nilé ẹjọ pé oun tọrọ aforiji nítori pe àṣìṣe ni kìí ṣe pé oun mọ̀ọ́mọ́ pa ọmọ náà.

Wọn fẹbi ẹ̀sùn ìpàniyan kan an ní inú oṣù keji ọdún pe ó fi tipatipa fún ọmọ oṣù mẹ́jọ̀, Enitan Salubi ni mílììkì mú ní tulàsì lágbegbe Glenarden ní inu oṣù kẹwàá ọdún 2016 ti ọmọ náà si gba ibẹ̀ lọ.

Ẹri láti ara àwọn ayàwòràn kọ̀rọ̀ ti wọn ń lẹ mọle fi han pe Adeleye jẹ alágbàtọ ọmọ tó n ba wọn gbéle, O gbiyanju láti fún ọmọ náà lóunjẹ, sùgbọ́n ti ó kọ láti gba ounjẹ náà ti obinrin yii si da ọmọ náà dubulẹ láti fún un lóunjẹ.

Adajọ to gbẹ́jọ náà Karen Mason sọ pe bó tilẹ̀ jẹ pe oun ni igbagbọ pé Adeleye kìí ṣe ènìyàn burukú tí ó fẹ pa ọmọ sùgbọ́n ó yẹ ki ó mọ pé igbésẹ̀ náà le gba ẹmi ọmọ.

Ọmọ Yoruba ni Oluremi Adeleye, dídá ọmọ kilẹ̀ sì jẹ aṣà láàrin awọn abiyamọ láti rii dáju pe ebi ò pa ọmọ.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI