Ẹ TUN WO AWỌN ỌMỌ YAHOO MẸTALA TỌWỌ TẸ L'ẸDO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 5, 2019

Ẹ TUN WO AWỌN ỌMỌ YAHOO MẸTALA TỌWỌ TẸ L'ẸDO

Bawọn gendekunrin ti wọn ko niṣẹ meji lasiko yi ju iṣẹ gbajua lori ẹrọ ayelujara ko ba tete jawọ lati wa iṣẹ min in ṣe, afaimọ ko ma jẹ pe awọn ajọ to n gbogun ti ṣiṣe kumọkumọ lorileede yi, EFCC ma tubọ gbọna min maa ṣe idajọ fun wọn.

Pẹlu ibinu la gbọ pe awọn EFCC fi n ko awọn eeyan naa lasiko yi, to si jẹ pe oriṣiriṣi dukia atawọn ayederu iwe ti wọn fi n lu jibiti ni wọn n gba lọwọ wọn.

Ana Satide la gbọ pe ọwọ awọn EFCC tun tẹ awọn gendekunrin mẹtala kan to je iṣẹ gbajuẹ ori ayelujara yi lawọn naa n ṣe. Nibi ti wọn ti lọọ ṣe faaji ara wọn ni otẹẹli kan to wa lagbegbe Uromi, nipinlẹ Ẹdo lọwọ si ti tẹ wọn laarọ kutkutu.

AWIKONKO gbọ pe awọn eeyan naa ni ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun si ọdun marundinlogoji lọ.

Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ wọn ni foonu olowo nla mẹtalelogun, kọmputa alagbeeka mẹta, mọto boginni mẹta ọtọọtọ ti i ṣe Lexus R330, C300 ati GLK 350 4Matic.

Ohun ta a gbọ ni pe awọn eeyan naa yoo foju bale ẹjọ pẹlu bi wọn ti ṣe jẹwọ pe lootọ, iṣẹ Yahoo lawọn fi n jẹun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI