IYAALE ILE POORA LOJU ỌNA AKURẸ SILUU EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 4, 2019

IYAALE ILE POORA LOJU ỌNA AKURẸ SILUU EKOO

Titi dasiko ti ẹ n ka iroyin yi ni wọn ṣi n wa iyaale ile kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ogunmọla Adejọkẹ Deborah, ẹni wọn loo kuro niluu Akurẹ, to si n lọ siluu Eko.

Ọmọ obinrin naa lo gbe e sori ẹka ayelujara ti Instagram pe lati ọjọ Wẹside to kọja yi ni iya oun ti kuro niluu Akurẹ to lọ, to si lọ siluu Eko, ṣugbọn ti wọn ko ti i ri dasiko yi.

Ere la gbọ pe awọn mọlẹbi iayaale ile naa kọkọ pe e, afigba ti ọrọ na fẹ ma a di toootọ. Eyi gan an lo mu ki ọmọ ẹ naa pariwo sita pe kawọn ọmọ Naijiria gba awọn.

O tun jẹ ko di mimọ pe awọn ko ti i gburo ẹnikẹni lati pe wọn boya wọn ji iya awọn gbe ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI