ṢE LOOOTỌ NI PE FADEYI OLORO TI KU? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 3, 2019

ṢE LOOOTỌ NI PE FADEYI OLORO TI KU?

Lati bi i wakati meloo kan sẹyin loro naa ti n lọ bi ahesọ kaakiri ori ẹrọ ayelujara pe gbajumọ oṣere to gbona nidi iṣẹ Babalawo, paapaa to tun fẹran lati maa jagun ninu sinima, ìyẹn Ojo Arowoṣafẹ, eni tọpọ mọ si Fadeyi Oloro ti dagbere faye.

Titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan la ko tii le fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni, ati pe gbogbo akitiyan lati fidi ẹ mulẹ lo n ja si pabo.

Okunrin kan, Alli Sulaiman Abiọdun to sọ pe ẹgbọn oun ni Fadeyi Oloro lo gbe iroyin naa sori eka ayelujara, gbajumọ oṣere naa ti ku, ti ko si sọ nkan to pa a.

Bẹ o ba gbagbe, loootọ ni pe ọkunrin naa ṣaisan laipẹ yi, ti wọn si ti fi silẹ lọsibitu pe ara rẹ ti ya, iyẹn lọjọ kẹwaa, oṣu kẹta ọdun yi.

Latigba naa lo ti dabi ẹni pe ko sẹni to fi bẹẹ gburo ẹ.

Ṣugbọn ni bayii, ibeere kan ṣoṣo t'awọn eeyan n beere ni pe 'nibo ni Fadeyi Oloro wa?', ati pe ṣe loootọ lo ti ku?


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI