KI LẸ MỌ NIPA OLOOGBE HUBERT OGUNDE??? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 3, 2019

KI LẸ MỌ NIPA OLOOGBE HUBERT OGUNDE???

Yoruba ni odo kii gun, ko ma ni orirun. Bẹẹ naa ni isẹ ere itage sise jẹ, tori Hubert Adedeji Ogunde ni ọpọ eeyan gba pe o bẹrẹ ere tiata lede Yoruba, eyi to wa di itẹwọgba lode oni.

Oniruuru ere itage to n kọni lọgbọn, pani lẹrin, to si tun n kọ ni lẹkọ ni Ogunde ti ṣe jade nigba aye rẹ, bẹẹ si ni awọn awo orin rẹ lo maa n gbe jade lati fi kilọ fun iwa ibajẹ lawujọ wa, paapa laye awọn oyinbo amunisin.
Bi Hubert Ogunde tilẹ ṣilẹ bora, sibẹ ko yẹ ka gbagbe awọn iṣẹ takun-takun to ti gbe ṣe lati ṣeranwọ fun aṣa, iṣe ati ede Yoruba ko ma baa parun, idi si ree taa fi gbọdọ mọ ohun kan tabi meji nipa irufẹ eeyan ti Ogunde jẹ.

Ohun to yẹ ko mọ nipa Hubert Ogunde:

* Ọjọ Kẹwaa, osu Keje, ọdun 1916, eyiun ọdun mejilelọgọrun (102) sẹyin ni Hubert Ogunde fi ori sọlẹ si ilu Ọ̀sọsà, nipinlẹ Ogun.

* Jeremiah Deinbọ ati Eunice Owotusan Ogunde lo se ọkọ rẹ wa sile aye, Olusọagutan si ni baba rẹ.

* Ọdọ baba iya rẹ to jẹ onifa, ni Hubert gbe fun igba kan, eyi to mu ko mọ nipa Ifa, Ogun atawọn orisa abalaye miran.

* Ogunde sisẹ lẹyin to pari iwe mẹfa rẹ tan bii olukọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ, ọga akọrin ni ṣọọsi ati atẹduru.

* Ẹgbẹ Eegun Alarinjo lo fi bẹrẹ isẹ tiata, ko to dara pọ mọ isẹ ọlọpaa, o si de ipo Kọsitebu, ko to fẹyinti.

* Oun lo kọkọ mu ere tiata wọ inu ẹgbẹ alarinjo, eyi to sọ di oludasilẹ ere tiata.

* Lara awọn ere onise to se ni ‘Human Parasites’, eyi to fi n tako iwa sisare lati ra asọ ẹbi olowo iyebiye tii se ara ara Yoruba.

* Ogunde jẹ ajijagbara fun iran Yoruba ati Naijiria, lati ipasẹ ọpọ ere to se fi tako awọn oyinbo amunisin. Lara ere naa ni ‘Bread and Bullet’ to se lọdun 1950.

* Ogunde tun maa n lo ede Gẹẹsi pọ mọ Yoruba lasiko to ba n gbe ere kalẹ.

* O se ere pẹlu orin Yoruba Ronu ati Otitọ Koro nibi ayẹyẹ kan ti Oloogbe SL Akintọla peju si, eyi to fi n sọko ọrọ nipa aawọ Akintọla ati Awolọwọ, ti Akintọla si binu jade nibẹ.
* Orin Yoruba Ronu wa lara idi to mu ki wọn kede ilu ko fara rọ lọdun 1963 lẹkun ilẹ Kaarọ Oojire.

* Ọdun meji ni wọn fi fi ofin de Ogunde lati se ere tiata lẹkun iwọ oorun Naijiria, tii se ilẹ Yoruba, amọ ijọba ologun ti Fajuyi leawaju rẹ lẹkun naa, lo gbẹsẹ kuro lori ofin ọhun.

* Lara awọn Sinima ti Ogunde gbe jade ni Aye ati Jayesinmi to si tun se awọn ere loniranran lori mohunmaworan nigba ti wọn si ileesẹ WNTV.

* Ogunde lee kọrin bii ẹni layin, ohun rẹ̀ rẹ̀dòdò, to si se awo orin to le ni aadọrun jade ati ere ori itage to le ni aadọta. Lara rẹ́ ni Ẹkun Oniwogbe, Onimọto, Yoruba Ronu.

* O kọ abule sinima kan si ilu rẹ Ọsọsa, eyi to jẹ apewawo. Ibẹ lo ti ya sinima Ayanmọ ati Aropin n teniyan, ibudo naa si wulo fun awọn osere tiata lode oni.

* Alagbo nla ni Ogunde, o ni ọpọ iyawo, to si bi ọmọ pupọ. Ọpọ wọn si lo maa n ba se ere tiata tabi kọ orin, tawọn ọmọ rẹ kan si n sere tiata di oni.

* Ogunde gba ọpọlọpọ ami ẹyẹ lati mọ riri isẹ takuntakun to se fun iran ọmọniyan ati ijijagbara iran Yoruba.

* Lẹyin to ya ere kan tan, to pe akọle rẹ ni ‘Mr Johnson’ ni Hubert Adedeji Ogunde dubulẹ aisan, to si juwọ si aye pe o digbose lọjọ Kẹrin, osu Kẹrin ọdun 1990 ni ilu London.

Yoruba ni ati oore, ati ika, ọkan kii gbe, nitori naa lo se yẹ ka se aye re.
Bo tilẹ jẹ pe Hubert Adedeji Ogunde ti waye, o ti se iwọn to lee se, ti ipa to fi lelẹ ninu idagbasoke igbe aye ọmọniyan ko si lee parẹ, o yẹ ki awa ta jẹ abẹmi loke eepẹ loni fi eyi se awokọse rere, ka si se aye re.

Bakan naa lo yẹ ka maa bi ara wa leere pe ti mo ba lọ tan, ki ni aye yoo maa wi nipa temi?

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI