Ẹ MA KOBA MI O, MI O LỌWỌ NINU IKU ṢUGAR O - GOMINA AJIMỌBI PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 3, 2019

Ẹ MA KOBA MI O, MI O LỌWỌ NINU IKU ṢUGAR O - GOMINA AJIMỌBI PARIWO SITA

Ko sẹni to gbọ bi Gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ṣe n sọrọ laipẹ yi, to si fẹẹ le maa sunkun pe ki wọn ma ṣe di ẹru ti ki i ṣe ti ẹ le oun lori, to si loun ko mọ ohunkohun nipa iku ọkan lara awọn aṣoju-ṣofin nipinlẹ naa, Ọnọrebu Temitọpẹ Ọlatoye ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Ṣugar.

Ni ọjọ idibo sipo gomina ni awọn agbenipa kan yinbọn pa Ọnọrebu Temitọpẹ Akintoye.

Lasiko eto isinku rẹ to waye ni gbọngan awọn lọbalọba niluu Ibadan ni ẹgbọn aṣofin naa Ọlajide Ọlatoye ti paroko ikilọ ranṣẹ si Gomina Ajimọbi pe ko jawọ igbesẹ to ni o n gbe lati tu awọn afunrasi ti wọn mu fun iku ẹgbọn rẹ silẹ.

O fi ẹsun kan an wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ n "Ṣehin-sọhun" laarin mọlẹbi oloogbe ati awọn apanilẹkun jaye naa.

Ọlajide fi kun ọrọ rẹ wi pe ohun ti o tọ ni ki ijọba ipinlẹ Ọyọ ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ jawọ ninu abosi, " bi wọn ko ba fẹ fi ọwọ ara wọn gbe ọmọ sin."

Amọṣa, Gomina Ajimọbi ni ko si otits ninu ọrọ naa ati pe ko si idi fun oun lati wa iku oloogbe naa tabi gbiyanju ati da apaadi bo ina eto idajọ lori iṣẹlẹ naa.

Ninu atẹjade kan to fi ran amugblẹgbẹ fun un lori eto ibanisọrọ, Bọlaji Tunji ni Gomina Ajimọbi ti ṣalaye eyi.

Ajimọbi ni ileri oun lati rii pe awọn to pa 'ṣugar' foju ba ina ofin, ileri naa ko si tii yẹ rara.

Ki o to ku, oloogbe Temitọpẹ Ọlatoye lo n ṣoju fun ẹkun idibo apapọ Lagelu/Akinyẹle ni ipinlẹ Ọyọ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI