LẸYIN TI BUHARI YỌ ORUKỌ RẸ KURO GẸGẸ BI MINISITA, FAṢỌLA GBE ORUKỌ AWỌN TO JẸ GBESE JADE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 5, 2019

LẸYIN TI BUHARI YỌ ORUKỌ RẸ KURO GẸGẸ BI MINISITA, FAṢỌLA GBE ORUKỌ AWỌN TO JẸ GBESE JADE

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, SERAP ti ri iwe gba lati ọwọ Minisita fun ọrọ isẹ ati ile gbigbe, Babatunde Fashọla to fi orukọ awọn ileeṣẹ to gba owo, amọ ti wọn kọ lati se iṣẹ naa.

Ninu atẹjade ti Ajọ SERAP gbe lede, Kọlawọle Oluwadare ni Fashọla fi ṣọwọ si wọn gẹgẹ bi ilana ofin to rọ mọ ‘Information Act’ ti orilẹede Naijiria to fọwọ si wi pe ti ọmọ Naijiria ba bẹrẹ iwadii kikun lori isẹlẹ, wọn gbọdọ fi lede.

Iwe ti wọn fi ransẹ si wọn naa fihan wipe "Pow Technologies Limited" to kalẹ si ilu Abuja kọ lati ko irinsẹ ti wọn fi n se ayẹwo ina ninu ile ati kaakiri ile isẹ NAPTIN ti wọn san miliọnu mọkandinlogoji fun ninu miliọnu mẹtadinlaadọrun, amọ ti wọn kọ lati ko irinsẹ naa wa.

Gẹgẹ bi ile isẹ to n risi ọrọ ile gbigbe ati isẹ se sọ, ọdun 2014 ni wọn ti gbe isẹ naa fun wọn, ti o si jẹ pe mẹtala ninu mọkandinlogun isẹ ti wọn gba ni wọn se.

Ajọ SERAP naa ni awọn ni asẹ lati ri iwe naa nitori asẹ ti awọn gba lati ile ẹjọ giga ni ilu Eko ni Osu Keji, ọdun 2019.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI