NGIJ BALẸ SIPINLẸ KOGI: IDAAMU DE BA GOMINA YAHAYA BELLO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, May 9, 2019

NGIJ BALẸ SIPINLẸ KOGI: IDAAMU DE BA GOMINA YAHAYA BELLO

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ẹgbẹ oniroyin to n ṣewadi kulẹkulẹ awọn iṣẹlẹ ni kikun lorileede Naijiria, iyẹn Nigeria Guild of Investigative Journalists (NGIJ) ti balẹ sipinlẹ Kogi.

Ki i ṣe pe awọn eeyan naa deede gbera lọ siluu Kogi, iyẹn ilu Lọkọja bi ko ṣe lati ṣewadi ni kikun lori iṣejọba Gomina Yahaya Bello lati bi ọdun meloo kan sẹyin.

Ẹgbẹ ti Aarẹ fidihẹ wọn, Kọmureedi Wale Abydeen, to jẹ ọga agba fun ileeṣẹ iroyin Security Monitor la gbọ pe o lewaju awọn ọmọ ẹgbẹ mẹsan an ti wọn yan lọ sipinlẹ Kogi.

Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ jẹ ko ye wa pe bi iroyin ṣe tẹ Gomina Yahaya lọwọ pe ẹgbẹ NGIJ ti wa niluu Lọkọja to jẹ olu-ipinlẹ naa lo ti bẹrẹ si i wa gbogbo ọna lati mọ ọna bi yoo ṣe bawọn eeyan naa ṣepade.

A gbọ pe kaakiri awọn ilu to wa nipinlẹ naa lawọn ọmọ ẹgbẹ NGIJ yi yoo lọ kaakiri lati fọrọ wa awọn araalu lẹnu wo lori awọn iwa ti Gomina Bello n hu, paapaa awọn ẹka ileeṣẹ ijọba ni wọn yoo de lati ṣewadi kikun.

Nigba to n b'AWIKONKO sọrọ, Kọmureedi Wale Abydeen jẹ ko di mimọ pe awọn wa nipinlẹ Kogi lati mọ awọn aṣeyọri iṣẹ Gomina Yahaya Bello, ati lati mọ iha tawọn araalu kọ si ijọba rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI