NITORI DAPỌ ABIỌDUN, WỌN DA DEISEL S'OJU ỌNA ILARO, L'AWỌN MỌTO BA N MU ORI WỌNU IGBO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 26, 2019

NITORI DAPỌ ABIỌDUN, WỌN DA DEISEL S'OJU ỌNA ILARO, L'AWỌN MỌTO BA N MU ORI WỌNU IGBO

Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laarọ oni Sande ba fi le je otitọ, a jẹ pe a fi k'awọn mọto ti wọn rin irin ajo loju ọna Ilaro maa ṣọ ara wọn pẹlu bi wọn  ṣe l'awọn mọto n mu ori wọnu igbo latari epo Diesel ti wọn l'awọn oṣika kan da soju ọna naa loru mọju.
Fawọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ nipinlẹ Ogun daadaa, paapaa nipa ti isipo pada ijọba to fẹẹ waye, wọn a mọ pe oni Sande jẹ eto isin fun ti bi Ọmọba Dapọ Abiọdun ti won yan dibo yan gẹgẹ bi Gomina yoo ṣe bọ sori aga.
Ṣọọṣi All Saints Anglican to wa loju ọna Leslie niluu Ilaro ni eto naa ti n waye dasiko tá a ṣakojọpọ iroyin yi tan.
AWIKONKO gbọ pe gbogbo ọna ni wọn l'awọn kan ti wọn ko fẹ ki eto naa ṣee ṣe nirọwọ irọsẹ n wa lati da wahala silẹ, ki wọn si ba eto naa jẹ, ko da, ti wọn ni wọn tún n fi iku wa Ọmọba Dapọ Abiọdun kaakiri.
Oru mọjumọ ni wọn l'awọn oṣika kan pinnu lati lọọ da ọkan lara awọn epo rọbii, iyẹn Diesel lati agbegbe Papalanto titi lọọ de ikorita ilu Ilaro, ti wọn sì tun da a lọ si ilu Ibeṣe ti ileeṣẹ Dangote wa.

Bó tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi ohun to ṣẹlẹ yi mulẹ, ṣugbọn wọn ni tanka epo meji to kun fun Diesel ni wọn lati le da ijamba ọkọ silẹ fun Dapọ Abiọdun at'awọn alejo ẹ nibi eto isin naa.
Pupọ ninu awọn mọto ti wọn kọja, to fi mọ tirela Dangote loriṣiriṣi la gbọ pe wọn mu ori wọnu igbo, ti wọn si l'awọn ọlọkada at'awọn ero wọn n ṣubu ṣere loju ọna naa.

Awọn kan ti ẹ fẹsun naa kan Gomina Ibikunle Amosun pe oun lo ran awọn eeyan naa n'iṣẹ lati da Diesel kaakiri oju ọna yi lati ṣakoba fun Dapọ Abiọdun at'awọn alejo ẹ, ṣugbọn ta a ko le fidi ẹ mulẹ.

Lara awọn ọlọkada to b'AWIKONKO sọrọ ni wọn fi ẹdun ọkan wọn han pe iwa ọdaju l'awọn to gbe ìgbésẹ naa hu, tori pe bi wọn ba n sọ pe awọn dẹ pampẹ silẹ fun eeyan buruku, eeyan rere naa yoo ṣalabapin níbẹ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI