ALATẸNUJẸ NI TINUBU - BỌDE GEORGE SỌKO ỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 25, 2019

ALATẸNUJẸ NI TINUBU - BỌDE GEORGE SỌKO ỌRỌ

Ọkan pataki ninu ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP) lorileede Naijiria, Oloye Bọde George ti bu ẹnu atẹ lu awọn iwa to fẹsun ẹ Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu, to si ni ọkanjua ati atẹnujẹ lo n yọ ọ lẹnu.

Ilu Ekoo ni Oloye Bọde George ti sọrọ naa nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹlu awọn oniroyi.

Nibẹ lo ti dahun ibeere loriṣiriṣi lori eto oṣelu Naijiria ati bi nkan ṣe ri lasiko yii, aapaa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Bode George jẹ ko ye awọn oniroyin pe Tinubu ko mọ pe ebi n pa awọn araalu rara, to si n wa ọkọ ilẹ Yoruba lọ sibi iparun ojiji. Bẹẹ lo tun sọ pe gbogbo ọrọ ipinlẹ Ekoo ni Aṣiwaju Tinubu ti ko pamọ funra rẹ.
Lasiko to n dahun ibeere lori bi awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ṣe n yalọ si ẹgbẹ oṣelu APC lasiko yii, Bọde George ni ẹgbẹ mejeeji yatọ sira wọn, ṣugbọn aimọkan lo n ṣe awọn to n salọ fun igbala ninu ẹgbẹ APC, nitori pe ijakulẹ ni wọn yoo pada ba pade basiko ba to.
Nigba ti Bode George n dahun ibeere lori ayajọ iṣẹjọba Alagbada ti Democracy Day tọdun 2019, o ni iran Yoruba ni lati kọgbọn sii fun itẹsiwaju to yẹ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Yoruba ni b'ọmọ ko ba ba itan, o maa ba arọba to jẹ baba itan. Asiko ti to ki a ma kọ awọn ọmọ  wa nipa ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin ni June 12 ati May 29."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI