NITORI FRANKLIN, AFAIMỌ KI ỌGA JAMB MA KO SI WAHALA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 12, 2019

NITORI FRANKLIN, AFAIMỌ KI ỌGA JAMB MA KO SI WAHALA

Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe ọmọdun mẹẹdogun (15years), Ekene Franklin lo yege ju lọ ninu idanwo aṣewọle sileewe giga, iyẹn JAMB eyi ti wọn gbe esi ẹ jade laipẹ yi lẹyin ọpọlọpọ ọjọ tawọn eeyan ti n reti ẹ.

Ọga agba patapata fun ajọ JAMB naa, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede nigba to n sọrọ lana, Satide, Abamẹta lo ti jẹ ko di mimọ pe awọn mẹta pere ni wọn yege julọ ninu idanwo naa, awọn mẹta naa lo pe ni Ekene Franklin, ọmọ ipinlẹ Abia to jẹ ọmọdun mẹẹdogun; Igban Emmanuel Chidiebube, ọmọdun mẹrindinlogun to wa lati ipinlẹ Abia ati Oluwo Isaac Ọlamilekan, ọmọdun mẹtadinlogun toun wa lati ipinlẹ Ọṣun.

O ni maaki 347 ni Ekene Franklin to ṣe ipo kinni gba, nigba ti Igban Emmanuel to ṣe ipokeji gba maaki 346, ti Igban Emmanue to ṣe ipo kẹta gba maaki 345.

Ninu ọrọ Ọjọgbọn Ishaq Oloyede lo ti jẹ ko di mimọ pe Ekene ko ni lanfaani lati wọle sileewe fasiti ipinlẹ Ekoo, Lagos State University to mu gẹgẹ bi ifẹ akọkọ to mu nitori pe ọjọ ori ẹ si kere ju ileewe naa lọ.Ohun tawọn eeyan n sọ kaakiri ori ayelujara bayii ni pe ko yẹ ki Ọjọgbọ Ishaq sọ iru ọrọ bẹẹ sita, ati pe ṣe lo yẹ ki wọn tun idanwo min in ṣe fọmọ naa, to ba si yege, ki wọn gba a sileewe to fẹ lati lọ, ko yẹ ki wọn wo ọgbọn ori ẹ, paapaa bo tun ṣe jẹ pe ọpọlọ tawọn ọmọ asiko yi n gbe waye kọja oye awọn agba min in latari aye to ti lu kara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI