AṢEKAGBA IDIJE PREMIER LEAGUE: LAARIN MAN CITY ATI LIVERPOOL - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 12, 2019

AṢEKAGBA IDIJE PREMIER LEAGUE: LAARIN MAN CITY ATI LIVERPOOL

"Oni lonii n jẹ, ẹni a bẹ lọwẹ" lọrọ to n tẹnu awọn ololufẹ ere bọọlu kaakiri agbaye n sọ, pẹlu idije to fẹẹ waye loni in.

Loni ọjọ kejila, oṣu karun un ni idije Premier League yoo wa s'ipari ti a o si mọ ikọ agbabọọlu ti yoo gba ife ẹyẹ naa laarin Manchester City ati Liverpool.

Liverpool fẹ gbiyanju lati di ikọ agbabọọlu keji ninu itan ti yoo gba ife ẹyẹ Premier League mọ ikọ to n siwaju lọwọ lọjọ ti idije naa pari.

Liverpool to n tele Manchester City pẹlu ami ayo kan yoo gbalejo Wolves ni papa iṣẹre Anfield nigba ti Man City yoo waako pẹlu Brighton ni deedee aago mẹta ọsan ọjọ Aiku.

Man City ti gbayo mọkanlelaadọrun un sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹtadinlogoji ti wọn ti gba ni saa yii nigba ti Liverpool gba goolu mejidindinlaadọrun sawọn.

Bakan naa, awọn mejeeji sun mọ ara wọn pẹkipẹki lori tabili Premier League lẹyin tu Man City n fi ami ayo marun le laadọrun siwaju ti Liverpool si wa ni ipo keji pẹlu ami ayo mẹrinlelaadọrun.

Igba kẹjọ re e ti idije ti ikọ to gba Premier League yoo foju han lọjọ ti idije naa pari.

Liverpool to ti pegede fun aṣekagba idije UEFA Champions League ko tii ri ife ẹyẹ Premier League fun ọgun mọkakandinlọgbọn bayii.

Ẹwẹ, akọnimọọgba Man City, Pep Guardiola ti sọ pe gbagbaagba bii ike lawọn alatilẹyin City yoo ṣe gbaruku ti wọn nigba ti wọn ba koju Brighton.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI